Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Self-Denial: General references

145 ẹsẹ · 41 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Abrahamu wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Abrahamu.” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

  2. Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Moria, kí o sì fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ.”

  3. Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì ṣẹ́ igi fún ẹbọ sísun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún un.

  4. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Abrahamu gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè,

  5. Abrahamu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ohunkóhun láti sin Ọlọ́run, a ó sì tún padà wá bá a yín.”

  6. Abrahamu sì gbé igi ẹbọ sísun náà ru Isaaki, òun fúnra rẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ. Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ,

  7. Isaaki sì sọ fún Abrahamu baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.” Abrahamu sì dalóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.” Isaaki sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?”

  8. Abrahamu sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì jùmọ̀ ń lọ.

  9. Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Abrahamu, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igi lé e lórí, ó sì di Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà.

  10. Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀.

  11. Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

  12. Angẹli Olúwa sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.”

  13. Ọba sì wí fún Arauna pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n èmi ó rà á ní iye kan lọ́wọ́ rẹ, bí ó ti wù kí ó ṣe; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi èyí tí èmi kò náwó fún, rú ẹbọ sísun sí Olúwa Ọlọ́run mi.” Dafidi sì ra ibi ìpakà náà, àti àwọn màlúù náà ní àádọ́ta ṣékélì fàdákà.

  14. Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ, bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi.

  15. Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi, tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,

  16. títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa, ibùjókòó fún alágbára Jakọbu.

  17. Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.

  18. Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun, bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.

  19. Èmi kì í jẹ oúnjẹ tí ó dára, èmi kò fi ẹran tàbí wáìnì kan ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fi kọjá.

  20. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.

  21. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì.

  22. Olùkọ́ òfin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí fún un pé, “Olùkọ́, èmi ó má tọ̀ ọ́ lẹ́yìn níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

  23. Jesu dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

  24. Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mìíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, kọ́kọ́ jẹ́ kí èmi kí ó kọ́ lọ sìnkú baba mi ná.”

  25. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú kí ó máa sin òkú ara wọn.”