Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Self-Denial: Christ set an example of

9 ẹsẹ · 41 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Christ set an example of

  1. Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án.

  2. Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”

  3. Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé, ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”

  4. Jesu dá lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ni ìtẹ́; ṣùgbọ́n Ọmọ Ènìyàn kò ní ibi tí yóò fi orí rẹ̀ lé.”

  5. Nítorí èmi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, kì í ṣe láti máa ṣe ìfẹ́ ti èmi fúnra mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.

  6. Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe ohun tí ó wu ara rẹ̀, ṣùgbọ́n bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mi.”

  7. Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run, kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.

  8. Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́, a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.

  9. Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, o sì tẹríba títí de ojú ikú, àní ikú lórí àgbélébùú.