Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Salvation

158 ẹsẹ · 106 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà.

  2. Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìyìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!”

  3. Bí ó bá sì ṣe pé nípa ti oore-ọ̀fẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti iṣẹ́ mọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ oore-ọ̀fẹ́ kì yóò jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe pé nípa ti iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti oore-ọ̀fẹ́ mọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, iṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ mọ́.

  4. Ǹjẹ́ mo ní, wọ́n ha kọsẹ̀ kí wọn kí ó lè ṣubú? Kí a má ri i, ṣùgbọ́n nípa ìṣubú wọn, ìgbàlà dé ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí, láti mú Israẹli jowú.

  5. bí ó le ṣe kí èmi kí ó lè mú àwọn ará mi jowú, àti kí èmi kí ó lè gba díẹ̀ là nínú wọn.

  6. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Israẹli là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ní Sioni ni Olùgbàlà yóò ti jáde wá, yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jakọbu.

  7. Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun, nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ.

  8. Nítorí pé òmùgọ̀ ni ọ̀rọ̀ àgbélébùú jẹ́ sí àwọn tí ń ṣègbé, ṣùgbọ́n fún àwa tí a ń gbàlà ó jẹ́ agbára Ọlọ́run.

  9. Nítorí pé, nínú ọgbọ́n Ọlọ́run, ayé kò le mọ̀ òun nípa ọgbọ́n àti ìṣeféfé wọn. Ó sì gba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ là nípa ìwàásù tí àwọn aráyé pè ní òmùgọ̀ àti ọ̀rọ̀ ọ yẹ̀yẹ́.

  10. Nítorí náà, bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni ti ó bá ń ṣògo kí ó máa ṣògo nínú Olúwa.”

  11. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí.

  12. Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jesu Kristi!

  13. Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé.

  14. Nítorí o wí pé, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ, àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.” Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà.

  15. Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá, ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú.

  16. ẹni tí ó fi òun tìkára rẹ̀ dípò ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè gbà wá kúrò nínú ayé búburú ìsinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,

  17. Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jesu Kristi Olúwa wa, nípasẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé.

  18. Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀,

  19. nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kristi, oore-ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là.

  20. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́. Èyí kì í ṣe nípa agbára ẹ̀yin fúnra yín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni,

  21. kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo.

  22. Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀.

  23. Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

  24. Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe àmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là.

  25. Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú.