Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Salvation: Of Israel, predicted
Àwọn ẹsẹ nípa Of Israel, predicted
Sọ fún àwọn oníbẹ̀rù ọkàn pé, “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù; Ọlọ́run yín yóò wá, òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san; pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́ òun yóò wá láti gbà yín là.”
Ṣùgbọ́n Israẹli ni a ó gbàlà láti ọwọ́ Olúwa pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé; a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín, títí ayé àìnípẹ̀kun.
Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà bí agbo ènìyàn rẹ̀: nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé, tí a gbé sókè bí àmì lórí ilẹ̀ rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Israẹli là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Ní Sioni ni Olùgbàlà yóò ti jáde wá, yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jakọbu.