Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rulers

255 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́ ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo.

  2. “Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ilé ayé ti ń wárìrì lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.

  3. Ìránṣẹ́ tí ó di ọba aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,

  4. “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli, kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì, kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle,

  5. kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí, kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n.

  6. “Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnra wọn fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun.

  7. Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”

  8. Mo sì tún rí ohun mìíràn ní abẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́, òdodo ni ó wà níbẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ni o wà níbẹ̀.

  9. Mo wí nínú ọkàn mi, “Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olódodo àti ènìyàn búburú, nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́, àti àsìkò ṣe ìdájọ́ gbogbo ìṣe.”

  10. Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò sì ní olùtùnú kankan, agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára, wọn kò sì ní olùtùnú kankan.

  11. Òtòṣì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó sàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn.

  12. Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀.

  13. Bí o bá rí tálákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú púpọ̀, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ lójú ni, síbẹ̀ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì.

  14. Níwọ́n ìgbà tí ọ̀rọ̀ ọba ni àṣẹ, ta ni ó le è sọ fún un wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

  15. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo ti rí, tí mo sì ń múlò ní ọkàn mi sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn. Ìgbà kan wà tí ẹnìkan ń ṣe olórí àwọn tókù fún ìpalára rẹ̀.

  16. Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn, irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.

  17. A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jùlọ, nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn ààyè tí ó kéré jùlọ.

  18. Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin, nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.

  19. Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ àti tí àwọn ọmọ-aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.

  20. Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọlọ́lá, àti tí àwọn ọmọ-aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ, fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmutípara.

  21. Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín, akẹgbẹ́ àwọn olè, gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri. Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.

  22. Àwọn ọ̀dọ́mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú àwọn obìnrin ń jẹ ọba lé wọn lórí. Háà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti ṣì yín lọ́nà, wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.

  23. Olúwa dojú ẹjọ́ kọ àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀. “Ẹ̀yin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi, ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.

  24. Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?” ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  25. Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ilé Israẹli àwọn ọkùnrin Juda sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀. Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí. Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.