Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rulers

255 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́.

  2. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu tálákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́?

  3. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsàájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin.

  4. Ẹ máa tẹríba fún gbogbo ìlànà ènìyàn nítorí ti Olúwa, ìbá à ṣe fún ọba tàbí fún olórí.

  5. Tàbí fún àwọn baálẹ̀, fún àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbẹ̀san lára àwọn tí ń ṣe búburú, àti fún ìyìn àwọn tí ń ṣe rere.