Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prophets

655 ẹsẹ · 128 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Israẹli, kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mose.

  2. Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà.

  3. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ké pe Olúwa nítorí àwọn ará Midiani.

  4. Olúwa fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: mo mú yín gòkè ti Ejibiti wá, láti oko ẹrú.

  5. Mo gbà yín kúrò nínú agbára Ejibiti àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn aninilára yín. Mo lé wọn kúrò ní iwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín.

  6. Mo wí fún un yín pé, ‘Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín; ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́rọ̀ sí ohun tí mo sọ.”

  7. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Gideoni, ó sì fun fèrè ìpè, láti pe àwọn ará Abieseri láti tẹ̀lé òun.

  8. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Jefta òun sì la Gileadi àti Manase kọjá. Ó la Mispa àti Gileadi kọjá láti ibẹ̀, ó tẹ̀síwájú láti bá àwọn ará Ammoni jà.

  9. Ẹ̀mí Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nígbà tí ó wà ní Mahane-Dani ní agbede-méjì Sora àti Eṣtaoli.

  10. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀.

  11. Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Aṣkeloni, ó pa ọgbọ̀n nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru.

  12. Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Eli wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ, nígbà tí wọ́n ń bẹ ní Ejibiti nínú ilé Farao.

  13. Samuẹli ọmọkùnrin náà ṣe òjíṣẹ́ níwájú Olúwa ní abẹ́ Eli. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ọ̀rọ̀ Olúwa ṣọ̀wọ́n: kò sì sí ìran púpọ̀.

  14. Nígbà náà ni Olúwa pe Samuẹli. Samuẹli sì dáhùn, “Èmi nìyí.”

  15. Ó sì sáré lọ sí ọ̀dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyí nítorí pé ìwọ pè mí.” Ṣùgbọ́n Eli wí fún un pé, “Èmi kò pè ọ́; padà lọ dùbúlẹ̀.” Nítorí náà ó lọ ó sì lọ dùbúlẹ̀.

  16. Olúwa sì tún pè é, “Samuẹli!” Samuẹli tún dìde ó tọ Eli lọ, ó sì wí pé, “Èmi nìyìí, nítorí tí ìwọ pè mí.” “Ọmọ mi, èmi kò pè ọ́, padà lọ dùbúlẹ̀.”

  17. Ní àkókò yìí Samuẹli kò tí ì mọ̀ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni a kò sì tí ì fi ọ̀rọ̀ Olúwa hàn án.

  18. Olúwa pe Samuẹli ní ìgbà kẹta, Samuẹli sì tún dìde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Eli ó sì wí pé, “Èmi nìyìí; nítorí tí ìwọ pè mí.” Nígbà náà ni Eli wá mọ̀ pé Olúwa ni ó ń pe ọmọ náà.

  19. Nítorí náà Eli sọ fún Samuẹli, “Lọ kí o lọ dùbúlẹ̀. Tí o bá sì pè ọ́, sọ wí pé, ‘Máa wí, Olúwa nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni Samuẹli lọ, ó sì lọ dùbúlẹ̀ ní ààyè rẹ̀.

  20. Olúwa wá, ó sì dúró níbẹ̀, ó pè é bí ó ṣe pè é ní ìgbà tí ó kọjá, “Samuẹli! Samuẹli!” Nígbà náà ni Samuẹli dáhùn pé, “Máa wí nítorí tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.”

  21. Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Israẹli tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro.

  22. Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.

  23. Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun.

  24. Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ”

  25. Olúwa wà pẹ̀lú Samuẹli bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà.