Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Praise

490 ẹsẹ · 106 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.

  2. Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú

  3. Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀

  4. Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀ ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́ ó sì mú odò rẹ̀ sàn.

  5. Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli.

  6. Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀ wọn ko mọ òfin rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

  7. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá, ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.

  8. Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀, ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀.

  9. Ẹ fi ìyìn fún un, oòrùn àti òṣùpá. Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.

  10. Ẹ fi ìyìn fún un, ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

  11. Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn

  12. Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

  13. Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá ẹ̀yin ẹ̀dá inú òkun títóbi àti ẹ̀yin ibú òkun,

  14. mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu, ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,

  15. òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèké, igi eléso àti gbogbo igi kedari,

  16. àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́,

  17. àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,

  18. ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

  19. Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run

  20. Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

  21. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa. Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

  22. Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní ayọ̀ nínú ọba wọn.

  23. Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀ jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.

  24. Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.

  25. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀ kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.