Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Praise

490 ẹsẹ · 106 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa. Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.

  2. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

  3. Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi, èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.

  4. Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé, àní, ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.

  5. Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀, ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo.

  6. Ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.

  7. Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.

  8. Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára, tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa, Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀,

  9. Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran, Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga, Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.

  10. Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.

  11. Olúwa jẹ ọba títí láé; Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

  12. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa, ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!

  13. Olúwa kọ́ Jerusalẹmu; Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.

  14. Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.

  15. Ó ka iye àwọn ìràwọ̀ ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ.

  16. Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára òye rẹ̀ kò sì ní òpin.

  17. Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.

  18. Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.

  19. Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀ ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè

  20. Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.

  21. Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin, bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin

  22. Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.

  23. Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu; yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.

  24. Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára, Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ

  25. Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀, òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.