- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Obedience to God
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Noa sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.
Olúwa sì wí fún Abramu, “Jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi yóò fihàn ọ́.
“Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, èmi yóò sì bùkún fún ọ; èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí.
Èmi yóò bùkún fún àwọn tí ó súre fún ọ, ẹni tí ó fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré; nínú rẹ ni a ó bùkún gbogbo ìdílé ayé.”
Bẹ́ẹ̀ ni Abramu lọ bí Olúwa ti sọ fún un. Lọti náà sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni àrùndínlọ́gọ́rin ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani.
Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì ṣẹ́ igi fún ẹbọ sísun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún un.
Angẹli Olúwa sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.”
Farao dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.”
Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose àti Aaroni.
Nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́ràn sí mi dé ojú àmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi.
Fi ara balẹ̀, kí o sì fetísílẹ̀ sí i, kí o sì gba ohùn rẹ̀ gbọ́; má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kò ní fi àìṣedéédéé yín jì yín, orúkọ mi wà lára rẹ̀.
Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì ṣe ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín. Èmi yóò sì fóòro àwọn tí ń fóòro yín.
Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí. Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.”
kò sí ẹnìkankan àyàfi Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissiti àti Joṣua ọmọ Nuni, nítorí wọ́n tẹ̀lé Olúwa tọkàntọkàn.’
Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ tí mo fún un yín lónìí tọkàntọkàn: tí ẹ fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì sìn ín, pẹ̀lú gbogbo àyà yín àti gbogbo ọkàn yín:
ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.
Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tí ì mọ̀.
Olúwa Ọlọ́run yín ni kí ẹ tẹ̀lé, Òun ni kí ẹ bu ọlá fún, ẹ pa òfin rẹ̀ mọ́ kí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, ẹ sìn ín, kí ẹ sì dìímú ṣinṣin.
Bí ìwọ bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní kíkún kí o sì kíyèsára láti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ó pàṣẹ tí mo fi fún ọ lónìí, Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ lékè ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ.
Gbogbo ìbùkún yìí yóò wá sórí rẹ yóò sì máa bá ọ lọ bí o bá gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Ìbùkún ni fún ọ ni ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.
Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ àti ìbísí i màlúù rẹ àti ọmọ àgùntàn rẹ.
Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ipò ìyẹ̀fun rẹ.
Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.
Olúwa yóò gbà fún ọ pé gbogbo ọ̀tá tí ó dìde sí ọ yóò bì ṣubú níwájú rẹ. Wọn yóò tọ̀ ọ́ wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n wọn yóò sá fún ọ ní ọ̀nà méje.