Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Obedience to God

143 ẹsẹ · 45 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo.

  2. Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ẹ̀yin ti jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ rí, ẹ̀yin jẹ́ olùgbọ́ran láti ọkàn wá sí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́.

  3. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìyìnrere. Nítorí Isaiah wí pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìyìn wa gbọ́?”

  4. Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

  5. Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti lànà rẹ̀ wá.

  6. Nítorí ìgbọ́ràn yín tànkálẹ̀ dé ibi gbogbo, nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú.

  7. Àwa ń sọ gbogbo èrò àti gbogbo ohun gíga ti ń gbe ara rẹ̀ ga sí ìmọ̀ Ọlọ́run kalẹ̀, àwa sì ń di gbogbo èrò ní ìgbèkùn wá sí ìtẹríba fún Kristi.

  8. Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu.

  9. Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run, kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.

  10. Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́, a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.

  11. Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, o sì tẹríba títí de ojú ikú, àní ikú lórí àgbélébùú.

  12. Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì,

  13. Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọ́ran nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀.

  14. Ṣùgbọ́n láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣe é ṣe láti wù ú; nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá kò lè ṣàì gbàgbọ́ pé ó ń bẹ, àti pé òun ní olùṣẹ̀san fún àwọn tí o fi ara balẹ̀ wá a.

  15. Nípa ìgbàgbọ́ ní Abrahamu, nígbà tí a ti pé e láti jáde lọ sí ibi tí òun yóò gbà fún ilẹ̀ ìní, ó gbọ́, ó sì jáde lọ, láì mọ ibi tí òun ń rè.

  16. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.

  17. àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi: Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín.

  18. Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́.