Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Martyrdom: General references

28 ẹsẹ · 20 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́ a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

  2. “Arákùnrin yóò sì fi arákùnrin fún pípa. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò ṣọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n.

  3. Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà.

  4. Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.

  5. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nítorí mi, yóò rí i.

  6. Nítorí náà èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn akọ̀wé sí yín. Ẹ̀yin yóò pa àwọn kan nínú wọn nípa kíkàn wọ́n mọ́ àgbélébùú. Ẹ̀yin yóò fi pàṣán na àwọn ẹlòmíràn nínú Sinagọgu yín, tí ẹ̀yin yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú.

  7. Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

  8. “Nígbà náà ni a ó sì dá a yín lóró. A ó pa yín, a ó sì kórìíra yín ni gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí pé ẹ̀yin jẹ́ tèmi.

  9. “Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn.

  10. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là.

  11. Kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí;

  12. A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀rẹ́; òun ó sì mú kì a pa nínú yín.

  13. A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi.

  14. Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun.

  15. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́; À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”

  16. Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.

  17. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú,

  18. Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Olódùmarè, ẹni mímọ́ àti olóòtítọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?”

  19. A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí a o pa bí wọn, yóò fi dé.

  20. Nígbà tí wọn bá sì ti parí ẹ̀rí wọn, ẹranko tí o ń tí inú ọ̀gbun gòkè wá yóò bá wọn jagun, yóò sì ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n.

  21. Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sodomu àti Ejibiti nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú.

  22. Fún ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ ni àwọn ènìyàn nínú ènìyàn gbogbo àti ẹ̀yà, àti èdè, àti orílẹ̀, wo òkú wọn, wọn kò si jẹ kì a gbé òkú wọn sínú ibojì.

  23. Àti àwọn tí o ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì yọ̀ lé wọn lórí, wọn yóò sì ṣe àríyá, wọn ó sì ta ara wọn lọ́rẹ; nítorí tí àwọn wòlíì méjèèjì yìí dá àwọn tí o ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lóró.

  24. Àti lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹsẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn.

  25. Wọn sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti ọ̀run wá ń wí fún wọn pé, “Ẹ gòkè wá ìhín!” Wọn sì gòkè lọ sí ọ̀run nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀; lójú àwọn ọ̀tá wọn.