Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Martyrdom: Prophets and Saints of old

5 ẹsẹ · 20 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Prophets and Saints of old

  1. Nígbà tí Jesebeli sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Obadiah sì mú ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn.

  2. Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí.”

  3. Kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí;

  4. láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí.

  5. A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn, wọ́n rìn káàkiri nínú awọ àgùntàn àti nínú awọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olùpọ́njú, ẹni tí a ń da lóró;