Fò sí àkóónú

circa AD 95

The Revelation

John's vision on Patmos unveils the cosmic victory of the Lamb over evil and the final restoration of all creation.

404 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìfihàn 21:20nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    ẹ̀karùnún, sardoniki; ẹ̀kẹfà, kaneliani; èkeje, krisoliti; ẹ̀kẹjọ, berili; ẹ̀kẹsànán, topasi; ẹ̀kẹwàá, krisoprasu; ẹ̀kọkànlá, jakiniti; èkejìlá, ametisiti.

  2. Ìfihàn 21:21nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnu ibodè méjèèjìlá jẹ́ perli méjìlá: olúkúlùkù ẹnu ibodè jẹ́ peali kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán.

  3. Ìfihàn 21:22nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn.

  4. Ìfihàn 21:23nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i, nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀.

  5. Ìfihàn 21:24nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀.

  6. Ìfihàn 21:25nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu ibodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán: nítorí ki yóò si òru níbẹ̀.

  7. Ìfihàn 21:26nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀.

  8. Ìfihàn 21:27nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-àgùntàn.

  9. Ìfihàn 22:1nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mi, tí ó mọ́ bí kirisitali, tí ń tí ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn jáde wá,

  10. Ìfihàn 22:2nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    ní àárín ìgboro rẹ̀, àti níhà èkínní kejì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so onírúurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà.

  11. Ìfihàn 22:3nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ègún kì yóò sì ṣí mọ: ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín.

  12. Ìfihàn 22:4nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀; orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni iwájú orí wọn.

  13. Ìfihàn 22:5nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Òru kì yóò sí mọ́; wọn kò sì ní wa ìmọ́lẹ̀ fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn: wọn ó sì máa jẹ ọba láé àti láéláé.

  14. Ìfihàn 22:6nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran angẹli rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.”

  15. Ìfihàn 22:7nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    “Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!”

  16. Ìfihàn 22:8nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.

  17. Ìfihàn 22:9nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!”

  18. Ìfihàn 22:10nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí, nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

  19. Ìfihàn 22:11nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì só; àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nì só; àti ẹni tí ń ṣe olódodo, kí ó máa ṣe òdodo nì só; àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nì só.”

  20. Ìfihàn 22:12nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    “Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán; èrè mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi, láti sán fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ yóò tí rí.

  21. Ìfihàn 22:13nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin.

  22. Ìfihàn 22:14nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    “Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni ẹ̀tọ́ láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu ibodè wọ inú ìlú náà.

  23. Ìfihàn 22:15nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké.

  24. Ìfihàn 22:16nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    “Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”

  25. Ìfihàn 22:17nǹkan bí 96 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.