Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Johanu 1:51nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni ó fi kún un pé, “Èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹ̀yin yóò rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àwọn angẹli Ọlọ́run yóò sì máa gòkè, wọ́n ó sì máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ Ènìyàn.”

  2. Johanu 2:1nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ kẹta, wọn ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kana ti Galili. Ìyá Jesu sì wà níbẹ̀.

  3. Johanu 2:2nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    A sì pe Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi ìgbéyàwó náà.

  4. Johanu 2:3nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí wáìnì sì tán, ìyá Jesu wí fún un pé, “Wọn kò ní wáìnì mọ́.”

  5. Johanu 2:4nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Jesu fèsì pé, “Arábìnrin ọ̀wọ́n, èéṣe tí ọ̀rọ̀ yìí fi kàn mí? Àkókò mi kò tí ì dé.”

  6. Johanu 2:5nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Ìyá rẹ̀ wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ ṣe ohunkóhun tí ó bá wí fún yín.”

  7. Johanu 2:6nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ọgbọ̀n jálá.

  8. Johanu 2:7nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Jesu wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.

  9. Johanu 2:8nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, “Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ alábojútó àsè lọ.” Wọ́n sì gbé e lọ;

  10. Johanu 2:9nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    alábojútó àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Alábojútó àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apá kan,

  11. Johanu 2:10nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà ní wọn a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinsin yìí.”

  12. Johanu 2:11nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Èyí jẹ́ àkọ́ṣe iṣẹ́ àmì, tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.

  13. Johanu 2:12nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapernaumu, Òun àti ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gbé ibẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.

  14. Johanu 2:13nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu,

  15. Johanu 2:14nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nínú tẹmpili wọ́n jókòó:

  16. Johanu 2:15nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹmpili, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó si ti tábìlì wọn ṣubú.

  17. Johanu 2:16nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.”

  18. Johanu 2:17nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”

  19. Johanu 2:18nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ lè fihàn wá, tí ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?”

  20. Johanu 2:19nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wó tẹmpili yìí palẹ̀, Èmi ó sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta.”

  21. Johanu 2:20nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ní àwọn Júù wí pé, “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta ni a fi kọ́ tẹmpili yìí, ìwọ ó ha sì tún un kọ ní ọjọ́ mẹ́ta?”

  22. Johanu 2:21nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n òun ń sọ ti tẹmpili ara rẹ̀.

  23. Johanu 2:22nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà nígbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rántí pé, ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n sì gba Ìwé Mímọ́, àti ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ gbọ́.

  24. Johanu 2:23nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ó sì wà ní Jerusalẹmu, ní àjọ ìrékọjá, lákokò àjọ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ àmì tí ó ṣe.

  25. Johanu 2:24nǹkan bí 4 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Jesu kò gbé ara lé wọn, nítorí tí ó mọ gbogbo ènìyàn.