circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Johanu 3:25nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni iyàn kan wà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu àti Júù kan nípa ti ìwẹ̀nù.
- Johanu 3:26nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì tọ Johanu wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Rabbi, ẹni tí ó ti wà pẹ̀lú rẹ lókè odò Jordani, tí ìwọ ti jẹ́rìí rẹ̀, wò ó, òun tẹ àwọn ènìyàn bọ omi, gbogbo ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ wá.”
- Johanu 3:27nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Johanu dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí nǹkan kan gbà, bí kò ṣe pé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá.
- Johanu 3:28nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin fúnra yín jẹ́rìí mi pé mo wí pé, ‘Èmi kì í ṣe Kristi náà, ṣùgbọ́n pé a rán mi síwájú rẹ̀.’
- Johanu 3:29nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó tí ó dúró tí ó sì ń gbóhùn rẹ̀, ó ń yọ̀ gidigidi nítorí ohùn ọkọ ìyàwó; nítorí náà ayọ̀ mi yí di kíkún.
- Johanu 3:30nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Òun kò lè ṣàì máa pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi kò lè ṣàìmá rẹlẹ̀.
- Johanu 3:31nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
“Ẹni tí ó ti òkè wá ju gbogbo ènìyàn lọ; ẹni tí ó ti ayé wá ti ayé ni, a sì máa sọ ohun ti ayé. Ẹni tí ó ti ọ̀run wá ju gbogbo ènìyàn lọ.
- Johanu 3:32nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Ohun tí ó ti rí tí ó sì ti gbọ́ èyí náà sì ni òun ń jẹ́rìí rẹ̀; kò sì sí ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀.
- Johanu 3:33nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó gba ẹ̀rí rẹ̀ fi èdìdì dì í pé, olóòtítọ́ ni Ọlọ́run.
- Johanu 3:34nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ẹni tí Ọlọ́run ti rán ń sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí tí Ọlọ́run fi Ẹ̀mí fún un láìsí gbèdéke.
- Johanu 3:35nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọ́wọ́.
- Johanu 3:36nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun, ẹni tí kò bá sì gba Ọmọ gbọ́, kì yóò rí ìyè, nítorí ìbínú Ọlọ́run ń bẹ lórí rẹ̀.”
- Johanu 4:1nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Àwọn Farisi sì gbọ́ pé, Jesu ni, ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀ ju Johanu lọ.
- Johanu 4:2nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu tìkára rẹ̀ kò ṣe ìtẹ̀bọmi bí kò ṣe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀,
- Johanu 4:3nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili.
- Johanu 4:4nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Òun sì ní láti kọjá láàrín Samaria.
- Johanu 4:5nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaria kan, tí a ń pè ní Sikari, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jakọbu ti fi fún Josẹfu, ọmọ rẹ̀.
- Johanu 4:6nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Kànga Jakọbu sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jesu nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jókòó létí kànga, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.
- Johanu 4:7nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Obìnrin kan, ará Samaria sì wá láti fà omi, Jesu wí fún un pé ṣe ìwọ yóò fún mi ni omi mu.
- Johanu 4:8nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra oúnjẹ.
- Johanu 4:9nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Obìnrin ará Samaria náà sọ fún un pé, “Júù ni ìwọ, obìnrin ará Samaria ni èmi. Èétirí tí ìwọ ń béèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaria ṣe pọ̀.)
- Johanu 4:10nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, àti ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ni omi mu’, ìwọ ìbá sì ti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”
- Johanu 4:11nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní igbá-ìfami tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jì, Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà?
- Johanu 4:12nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Ìwọ pọ̀ ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí òun tìkára rẹ̀ si mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀?”
- Johanu 4:13nǹkan bí 30 lẹ́yìn Kristi
Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òǹgbẹ yóò sì tún gbẹ ẹ́.