Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Johanu 1:26nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Johanu dá wọn lóhùn, wí pé, “Èmi ń fi omi bamitiisi, ẹnìkan dúró láàrín yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀,

  2. Johanu 1:27nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”

  3. Johanu 1:28nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Betani ní òdìkejì odò Jordani, níbi tí Johanu ti ń fi omi bamitiisi.

  4. Johanu 1:29nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!

  5. Johanu 1:30nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi, tí ó pọ̀jù mí lọ, nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’

  6. Johanu 1:31nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.”

  7. Johanu 1:32nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Johanu jẹ́rìí sí i pé, “Mo rí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e.

  8. Johanu 1:33nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Èmi kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’

  9. Johanu 1:34nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”

  10. Johanu 1:35nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Ní ọjọ́ kejì, Johanu dúró pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

  11. Johanu 1:36nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì rí Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”

  12. Johanu 1:37nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jesu lẹ́yìn.

  13. Johanu 1:38nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Jesu yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin ń wá?” Wọ́n wí fún un pé, “Rabbi” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe Olùkọ́ni), “Níbo ni ìwọ ń gbé?”

  14. Johanu 1:39nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.” Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.

  15. Johanu 1:40nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Anderu arákùnrin Simoni Peteru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó sì tọ Jesu lẹ́yìn.

  16. Johanu 1:41nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Ohun àkọ́kọ́ tí Anderu ṣe ni láti wá Simoni arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Messia” (ẹni tí ṣe Kristi).

  17. Johanu 1:42nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu. Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).

  18. Johanu 1:43nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

  19. Johanu 1:44nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Filipi gẹ́gẹ́ bí i Anderu àti Peteru, jẹ́ ará ìlú Betisaida.

  20. Johanu 1:45nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”

  21. Johanu 1:46nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Natanaeli béèrè pé, “Nasareti? Ohun rere kan ha lè ti ibẹ̀ jáde?” Filipi wí fún un pé, “Wá wò ó.”

  22. Johanu 1:47nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Jesu rí Natanaeli ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Israẹli tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”

  23. Johanu 1:48nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Natanaeli béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?” Jesu sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Filipi tó pè ọ́.”

  24. Johanu 1:49nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Natanaeli sọ ọ́ gbangba pé, “Rabbi, ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni ọba Israẹli.”

  25. Johanu 1:50nǹkan bí 5 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀jù ìwọ̀nyí lọ.”