circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 24:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.
- Luku 24:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fi fún wọn.
- Luku 24:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n, ó sì nù mọ́ wọn ní ojú.
- Luku 24:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”
- Luku 24:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn.
- Luku 24:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!”
- Luku 24:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mí mọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.
- Luku 24:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jesu tìkára rẹ̀ dúró láàrín wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.”
- Luku 24:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì wárìrì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan.
- Luku 24:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí èròkerò fi ń sọ nínú ọkàn yín?
- Luku 24:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkára mi ni! Ẹ dì mímú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”
- Luku 24:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n.
- Luku 24:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhìn-ín yìí?”
- Luku 24:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè.
- Luku 24:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn.
- Luku 24:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé, a ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mose, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Saamu, nípasẹ̀ mi.”
- Luku 24:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni ó ṣí wọn ní iyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn.
- Luku 24:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: kí Kristi jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ọjọ́ kẹta kúrò nínú òkú,
- Luku 24:47nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu lọ.
- Luku 24:48nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.
- Luku 24:49nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èmi yóò rán ohun tí Baba mi ṣe ìlérí sí yín, ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerusalẹmu, títí a ó fífi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá.”
- Luku 24:50nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì mú wọn jáde lọ títí wọ́n fẹ́rẹ̀ dé Betani, nígbà tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn.
- Luku 24:51nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì ṣe, bí ó ti ń súre fún wọn, ó yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, a sì gbé e lọ sí ọ̀run.
- Luku 24:52nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì padà lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ayọ̀ púpọ̀.
- Luku 24:53nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì wà ní tẹmpili nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìyìn, àti ìbùkún fún Ọlọ́run.