circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Luku 23:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.”
- Luku 23:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un.
- Luku 23:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.”
- Luku 23:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe: Èyí ni Ọba àwọn Júù.
- Luku 23:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.”
- Luku 23:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà?
- Luku 23:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwa ṣe ni à ń jẹ, ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.”
- Luku 23:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì wí pé, “Jesu, rántí mi nígbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.”
- Luku 23:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Paradise!”
- Luku 23:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́.
- Luku 23:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Òòrùn sì ṣú òòkùn, aṣọ ìkélé ti tẹmpili sì ya ní àárín méjì.
- Luku 23:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Jesu sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.
- Luku 23:47nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!”
- Luku 23:48nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé.
- Luku 23:49nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili wá, wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí.
- Luku 23:50nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Josẹfu, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatea. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòtítọ́.
- Luku 23:51nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; Ó wá láti Judea, ìlú àwọn ará Arimatea, òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run.
- Luku 23:52nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu.
- Luku 23:53nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí.
- Luku 23:54nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀.
- Luku 23:55nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Galili wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsi ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀.
- Luku 23:56nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọ́n sì padà, wọ́n pèsè ohun olóòórùn dídùn, òróró ìkunra (àti tùràrí tútù); wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí òfin.
- Luku 24:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ ọ̀sẹ̀, àwọn obìnrin wá sí ibojì, wọ́n sì mú ìkunra olóòórùn dídùn ti wọ́n tí pèsè sílẹ̀ wá.
- Luku 24:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Òkúta ti yí kúrò ní ẹnu ibojì.
- Luku 24:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọ́n sì wọ inú rẹ̀, wọn kò rí òkú Jesu Olúwa.