Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Luku 24:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí wọ́n ti dààmú kiri níhà ibẹ̀, kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì aláṣọ dídán dúró tì wọ́n.

  2. Luku 24:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ẹ̀rù ń bà wọ́n, tí wọ́n sì dojúbolẹ̀, àwọn angẹli náà bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá alààyè láàrín àwọn òkú?

  3. Luku 24:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Kò sí níhìn-ín yìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Galili.

  4. Luku 24:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Pé, ‘A ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́, a ó sì kàn án mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.’ ”

  5. Luku 24:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì rántí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

  6. Luku 24:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì padà ti ibojì wá, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún àwọn mọ́kànlá, àti fún gbogbo àwọn ìyókù.

  7. Luku 24:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Maria Magdalene, àti Joanna, àti Maria ìyá Jakọbu, àti àwọn mìíràn pẹ̀lú wọn sì ni àwọn tí ó ròyìn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn aposteli.

  8. Luku 24:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì dàbí ìsọkúsọ lójú wọn, wọn kò sì gbà wọ́n gbọ́.

  9. Luku 24:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Peteru dìde, ó súré lọ sí ibojì; nígbà tí ó sì bẹ̀rẹ̀, ó rí aṣọ àlà lọ́tọ̀ fúnra wọn, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ẹnu yà á sí ohun tí ó ṣe.

  10. Luku 24:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Sì kíyèsi i, àwọn méjì nínú wọn ń lọ ní ọjọ́ náà sí ìletò kan tí a ń pè ní Emmausi, tí ó jìnnà sí Jerusalẹmu níwọ̀n ọgọ́ta ibùsọ̀.

  11. Luku 24:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣẹlẹ̀.

  12. Luku 24:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bá ara wọn jíròrò, Jesu tìkára rẹ̀ súnmọ́ wọn, ó sì ń bá wọn rìn lọ.

  13. Luku 24:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n a rú wọn lójú, kí wọn má le mọ̀ ọ́n.

  14. Luku 24:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì bi wọ́n pé, “Ọ̀rọ̀ kín ni ẹ̀yin ń bá ara yín sọ, bí ẹ̀yin ti ń rìn?” Wọ́n sì dúró jẹ́, wọ́n fajúro.

  15. Luku 24:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ọ̀kan nínú wọn, tí a ń pè ní Kileopa, sì dáhùn wí fún un pé, “Àlejò sá à ni ìwọ ní Jerusalẹmu, tí ìwọ kò sì mọ ohun tí ó ṣẹ̀ níbẹ̀ ní ọjọ́ wọ̀nyí?”

  16. Luku 24:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì bi wọ́n pé, “Kín ni?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Ní ti Jesu ti Nasareti, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì, tí ó pọ̀ ní ìṣe àti ní ọrọ̀ níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn,

  17. Luku 24:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    àti bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn alàgbà wa ti fi òun lé wọn lọ́wọ́ láti dá a lẹ́bi ikú, àti bí wọ́n ti kàn án mọ́ àgbélébùú.

  18. Luku 24:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni òun ni àwa ti ní ìrètí pé, òun ni ìbá dá Israẹli ní ìdè. Àti pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, òní ni ó di ọjọ́ kẹta tí nǹkan wọ̀nyí ti ṣẹlẹ̀.

  19. Luku 24:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn obìnrin kan pẹ̀lú nínú ẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lọ si ibojì ní kùtùkùtù, sì wá yà wá lẹ́nu,

  20. Luku 24:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn angẹli tí wọ́n wí pé, ó wà láààyè.

  21. Luku 24:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí, ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ ni wọn kò rí.”

  22. Luku 24:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́,

  23. Luku 24:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    kò ha yẹ kí Kristi ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.”

  24. Luku 24:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mose àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.

  25. Luku 24:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ, ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú.