circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 25:21nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Edomu, Moabu àti Ammoni;
- Jeremiah 25:22nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
gbogbo àwọn ọba Tire àti Sidoni; gbogbo àwọn ọba erékùṣù wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ìkọjá Òkun.
- Jeremiah 25:23nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Dedani, Tema, Busi àti gbogbo àwọn tí ń gbé lọ́nà jíjìn réré.
- Jeremiah 25:24nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn ọba àwọn àjèjì ènìyàn tí ń gbé inú aginjù.
- Jeremiah 25:25nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ọba Simri, Elamu àti Media.
- Jeremiah 25:26nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Àti gbogbo àwọn ọba àríwá ní tòsí àti lọ́nà jíjìn, ẹnìkínní lẹ́yìn ẹnìkejì; gbogbo àwọn ìjọba lórí orílẹ̀ ayé. Àti gbogbo wọn, ọba Ṣeṣaki náà yóò sì mu.
- Jeremiah 25:27nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
“Nígbà náà, sọ fún wọn, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí. Mu, kí o sì mú àmuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárín yín.
- Jeremiah 25:28nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba ago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún!
- Jeremiah 25:29nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀-èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò ha a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’
- Jeremiah 25:30nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
“Nísinsin yìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn: “ ‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá, yóò sì bú kíkankíkan sí ilẹ̀ náà. Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí.
- Jeremiah 25:31nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé, nítorí pé Olúwa yóò mú ìdààmú wá sí orí àwọn orílẹ̀-èdè náà, yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn, yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ” ni Olúwa wí.
- Jeremiah 25:32nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn; ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.”
- Jeremiah 25:33nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.
- Jeremiah 25:34nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn, ẹ yí nínú eruku, ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran. Nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé, ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye.
- Jeremiah 25:35nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Àwọn olùṣọ́-àgùntàn kì yóò rí ibi sálọ kì yóò sì ṣí àsálà fún olórí agbo ẹran.
- Jeremiah 25:36nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn, àti ìpohùnréré ẹkún àwọn olórí agbo ẹran; nítorí pé Olúwa ń pa pápá oko tútù wọn run.
- Jeremiah 25:37nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Ibùgbé àlàáfíà yóò di ahoro, nítorí ìbínú ńlá Olúwa.
- Jeremiah 25:38nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí kìnnìún yóò fi ibùba rẹ̀ sílẹ̀, ilẹ̀ wọn yóò sì di ahoro, nítorí idà àwọn aninilára, àti nítorí ìbínú ńlá Olúwa.
- Jeremiah 26:1nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìjọba ọba Jehoiakimu ọmọ Josiah tí ń ṣe ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa:
- Jeremiah 26:2nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
“Èyí ni ohun tí Olúwa wí, Dúró ní àgbàlá ilé Olúwa, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Juda tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé Olúwa, sọ fún gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà.
- Jeremiah 26:3nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n.
- Jeremiah 26:4nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé kalẹ̀ níwájú yín,
- Jeremiah 26:5nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
àti tí ẹ kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín léraléra (ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́),
- Jeremiah 26:6nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ ”
- Jeremiah 26:7nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremiah tí ó sọ ní ilé Olúwa.