Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jeremiah 24:6nǹkan bí 598 ṣáájú Kristi

    Ojú mi yóò máa ṣọ́ wọn lọ fún rere, Èmi yóò gbé wọn ró, n kò ní já wọn lulẹ̀. Èmi yóò gbìn wọ́n, n kò sì ní fà wọ́n tu.

  2. Jeremiah 24:7nǹkan bí 598 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, “Èmi ni Olúwa.” Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi; Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn; nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.

  3. Jeremiah 24:8nǹkan bí 598 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ,’ ni Olúwa wí, ‘bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Sedekiah ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jerusalẹmu, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Ejibiti.

  4. Jeremiah 24:9nǹkan bí 598 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sọ wọ́n di ìwọ̀sí àti ẹni ibi nínú gbogbo ìjọba ayé, láti di ẹni ìfibú àti ẹni òwe, ẹni ẹ̀sín, àti ẹni ẹ̀gàn ní ibi gbogbo tí Èmi ó lé wọn sí.

  5. Jeremiah 24:10nǹkan bí 598 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí wọn, títí tí gbogbo wọn yóò parun lórí ilẹ̀ tí a fún wọn àti fún àwọn baba wọn.’ ”

  6. Jeremiah 25:1nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremiah wá nípa àwọn ènìyàn Juda ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadnessari ọba Babeli.

  7. Jeremiah 25:2nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, Jeremiah wòlíì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti sí àwọn olùgbé Jerusalẹmu.

  8. Jeremiah 25:3nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Fún odidi ọdún mẹ́tàlélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.

  9. Jeremiah 25:4nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.

  10. Jeremiah 25:5nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì wí pé, “Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí Olúwa fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé.

  11. Jeremiah 25:6nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n; ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe. Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi.”

  12. Jeremiah 25:7nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ti mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ fi ọwọ́ yín ṣe, ẹ sì ti mú ibi wá sórí ara yín.”

  13. Jeremiah 25:8nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ èyí: “Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,

  14. Jeremiah 25:9nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátápátá, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé.

  15. Jeremiah 25:10nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà.

  16. Jeremiah 25:11nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Gbogbo orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì sìn ọba Babeli ní àádọ́rin ọdún.

  17. Jeremiah 25:12nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    “Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé, Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Babeli àti orílẹ̀-èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Babeli nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé.

  18. Jeremiah 25:13nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ àní gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremiah ti sọtẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè.

  19. Jeremiah 25:14nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Àwọn fúnra wọn yóò sì sin orílẹ̀-èdè púpọ̀ àti àwọn ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

  20. Jeremiah 25:15nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí fún mi: “Gba ago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè ti mo rán ọ sí mu ún.

  21. Jeremiah 25:16nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n: bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí yóò ránṣẹ́ sí àárín wọn.”

  22. Jeremiah 25:17nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Mo sì gba ago náà lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó rán mi sí mu ún.

  23. Jeremiah 25:18nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Jerusalẹmu àti àwọn ìlú Juda, àwọn ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí.

  24. Jeremiah 25:19nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Farao ọba Ejibiti, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

  25. Jeremiah 25:20nǹkan bí 606 ṣáájú Kristi

    Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjèjì tí ó wà níbẹ̀; gbogbo àwọn ọba Usi, gbogbo àwọn ọba Filistini, gbogbo àwọn ti Aṣkeloni, Gasa, Ekroni àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Aṣdodu.