- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 605–538 BC
The Babylonian Exile
Jerusalem falls and the temple burns; Ezekiel and Daniel minister among the exiles as Lamentations mourns the city's ruin.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Daniẹli 9:23nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Bí o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí nígbà àdúrà, a fún ọ ní ìdáhùn kan, èyí tí mo wá láti sọ fún ọ, nítorí ìwọ jẹ́ àyànfẹ́ gidigidi. Nítorí náà, gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò kí ìran náà sì yé ọ:
- Daniẹli 9:24nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
“Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ àti fún àwọn ìlú mímọ́ rẹ láti parí ìrékọjá, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, láti ṣe ètùtù sí ìwà búburú, láti mú òdodo títí ayé wá, láti ṣe èdìdì ìran àti wòlíì àti láti fi òróró yan Ibi Mímọ́ Jùlọ.
- Daniẹli 9:25nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
“Nítorí náà, mọ èyí pé, láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jerusalẹmu ṣe, kí a sì tún kọ́, títí dé ìgbà ọmọ-aládé, ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni.
- Daniẹli 9:26nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó ké Ẹni òróró náà kúrò, kò sì ní ní ohun kan. Àwọn ènìyàn ọmọ-aládé náà tí yóò wá ni yóò pa ìlú náà àti ibi mímọ́ run. Òpin yóò dé bí ìkún omi, ogun yóò máa jà títí dé òpin, a sì ti pàṣẹ ìdahoro.
- Daniẹli 9:27nǹkan bí 538 ṣáájú Kristi
Yóò sì fi ìdí i májẹ̀mú kan múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ní àárín ọ̀sẹ̀ ni yóò mú òpin bá ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Àti lórí apá kan ni yóò dà ìríra tí ó mú ìdahoro wá, títí tí òpin tí a ti pàṣẹ lórí asọnidahoro yóò fi padà fi dé bá a.”
- Daniẹli 10:1nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ní ọdún kẹta Kirusi ọba Persia, a fi ìran kan hàn Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belteṣassari). Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran.
- Daniẹli 10:2nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ní àsìkò náà, èmi Daniẹli ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta.
- Daniẹli 10:3nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Èmi kì í jẹ oúnjẹ tí ó dára, èmi kò fi ẹran tàbí wáìnì kan ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fi kọjá.
- Daniẹli 10:4nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù àkọ́kọ́, bí mo ti dúró sí etí i bèbè odò ńlá Tigirisi,
- Daniẹli 10:5nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
mo wo òkè, mo rí ọkùnrin kan tí ó wọ aṣọ àlà, ẹ̀gbẹ́ ẹni tí a fi wúrà Upasi dáradára dì ní àmùrè.
- Daniẹli 10:6nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ara rẹ̀ dàbí berili, ojú u rẹ̀ dàbí mọ̀nàmọ́ná, ẹyin ojú u rẹ̀ dàbí iná àtẹ̀tàn, apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí ìtànná ìmọ́lẹ̀ tí o kún fún idẹ, àti ohùn rẹ̀ dàbí i ti ìjọ ènìyàn púpọ̀.
- Daniẹli 10:7nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Èmi Daniẹli, ni ẹnìkan tí ó rí ìran náà, àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú u mi, wọn kò rí i, ṣùgbọ́n ìpayà ńlá dà bò wọ́n, wọ́n sálọ wọ́n sì fi ara pamọ́.
- Daniẹli 10:8nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ó sì ku èmi nìkan, tí mo rí ìran ńlá yìí, kò sì ku okun kankan fún mi, ojú u mi sì rẹ̀wẹ̀sì gidigidi, n kò sì ní agbára mọ́.
- Daniẹli 10:9nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, bí mo ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí i, mo sùn lọ fọnfọn, ní ìdojúbolẹ̀.
- Daniẹli 10:10nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ọwọ́ kan kàn mí, ó gbé mi dìde ní ìwárìrì lórí ọwọ́ àti eékún mi.
- Daniẹli 10:11nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ó sọ pé, “Daniẹli ẹni tí a yàn fẹ́ gidigidi gba ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ yìí yẹ̀ wò dáradára, kí o sì dìde, nítorí tí a rán mi sí ọ.” Bí ó ṣe sọ èyí fún mi, mo dìde ní ìwárìrì.
- Daniẹli 10:12nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ó tẹ̀síwájú, pé, “Má ṣe bẹ̀rù Daniẹli. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fi ọkàn rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì wá nítorí ọ̀rọ̀ náà.
- Daniẹli 10:13nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ọmọ-aládé ìjọba Persia dá mi dúró fún ọjọ́ mọ́kànlélógún. Nígbà náà ni Mikaeli, ọ̀kan lára ìjòyè àwọn ọmọ-aládé, wá láti ràn mi lọ́wọ́, nítorí a dá mi dúró níbẹ̀ pẹ̀lú ọba Persia.
- Daniẹli 10:14nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ní ìsinsin yìí mo wá láti ṣàlàyé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú, nítorí ìran náà ń sọ nípa ọjọ́ iwájú.”
- Daniẹli 10:15nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Bí ó sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún mi, mo sì dorí kodò mo sì dákẹ́.
- Daniẹli 10:16nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, ni ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kan ètè mi, mo la ẹnu mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀, mo sọ fún ẹni tí ó dúró níwájú mi, “Ìrònú sì mú mi, nítorí ìran náà, olúwa mi, n kò sì ní okun.
- Daniẹli 10:17nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ báwo ni èmi ìránṣẹ́ ẹ̀ rẹ ṣe lè bá ọ sọ̀rọ̀, olúwa mi? Agbára mi ti lọ, agbára káká ni mo fi ń mí.”
- Daniẹli 10:18nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ẹ̀wẹ̀, ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi ní agbára.
- Daniẹli 10:19nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Ó sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ ọkùnrin olùfẹ́ gidigidi. Àlàáfíà ni fún ọ, mú ara le, àní mú ara le.” Nígbà tí ohun bá mi sọ̀rọ̀, a sì mú mi lára le. “Mo sì wí pé, kí olúwa mi kí ó máa sọ̀rọ̀, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ ti mú mi ní ara le.”
- Daniẹli 10:20nǹkan bí 534 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, ni ó wí pé, “Ṣé o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá? Láìpẹ́ èmi yóò yípadà lọ bá àwọn ọmọ-aládé Persia jà, nígbà tí mo bá lọ àwọn ọmọ-aládé Giriki yóò wá;