Fò sí àkóónú

circa 1050–1010 BC

Samuel & King Saul

Israel demands a king; Samuel anoints Saul, whose disobedience leads to his rejection as God chooses a man after his own heart.

810 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. 1 Samuẹli 3:12nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.

  2. 1 Samuẹli 3:13nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun.

  3. 1 Samuẹli 3:14nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ”

  4. 1 Samuẹli 3:15nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Samuẹli dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Eli.

  5. 1 Samuẹli 3:16nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Eli pè é, ó sì wí pé, “Samuẹli, ọmọ mi.” Samuẹli sì dáhùn pé, “Èmi nìyìí.”

  6. 1 Samuẹli 3:17nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Eli béèrè pé, “Kín ni ohun tí ó sọ fún ọ?” “Má ṣe fi pamọ́ fún mi. Kí Ọlọ́run mi ṣe bẹ́ẹ̀ sí ọ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ bá fi ohunkóhun tí ó wí fún ọ pamọ́ fún mi.”

  7. 1 Samuẹli 3:18nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Samuẹli sọ gbogbo rẹ̀ fún un, kò sì fi ohun kankan pamọ́ fún un. Nígbà náà Eli wí pé, “Òun ni Olúwa; jẹ́ kí ó ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀.”

  8. 1 Samuẹli 3:19nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Olúwa wà pẹ̀lú Samuẹli bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà.

  9. 1 Samuẹli 3:20nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Gbogbo Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba mọ̀ pé a ti fa Samuẹli kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Olúwa.

  10. 1 Samuẹli 3:21nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara hàn án ní Ṣilo, nítorí Olúwa ti fi ará hàn án fún Samuẹli ní Ṣilo nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

  11. 1 Samuẹli 4:1nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Samuẹli tọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli wá. Nísinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli jáde láti lọ bá àwọn Filistini jà. Àwọn ọmọ Israẹli sì pàgọ́ sí Ebeneseri àti àwọn Filistini ní Afeki.

  12. 1 Samuẹli 4:2nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Àwọn Filistini mú ogun wọn sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Israẹli, nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Filistini ṣẹ́gun Israẹli wọ́n pa ẹgbàajì (4,000) ọkùnrin nínú ogun náà.

  13. 1 Samuẹli 4:3nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbàgbà Israẹli sì béèrè pé, “Èéṣe ti Olúwa fi mú kí àwọn Filistini ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa láti Ṣilo wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbà wá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”

  14. 1 Samuẹli 4:4nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà a rán àwọn ènìyàn lọ sí Ṣilo, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá, ẹni tí ń wà láàrín àwọn Kérúbù àti àwọn ọmọ Eli méjèèjì Hofini àti Finehasi wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.

  15. 1 Samuẹli 4:5nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dìde láti kígbe tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ sì mì tìtì.

  16. 1 Samuẹli 4:6nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Ní ìgbà tí àwọn Filistini gbọ́ ariwo náà wọ́n béèrè pé, “Kí ni gbogbo ariwo yìí ní ibùdó Heberu?” Nígbà tí wọ́n mọ̀ wí pé àpótí ẹ̀rí Olúwa ti wá sí ibùdó,

  17. 1 Samuẹli 4:7nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    àwọn Filistini sì bẹ̀rù pé, Ọlọ́run kékeré ti wọ ibùdó, wọ́n wí pé, “A wọ wàhálà, irú èyí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí.

  18. 1 Samuẹli 4:8nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Àwa gbé! Ta ni yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ Ọlọ́run alágbára yìí? Àwọn ni Ọlọ́run tí ó fi ìpọ́njú pa àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo àjàkálẹ̀-ààrùn ní aginjù.

  19. 1 Samuẹli 4:9nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Ẹ jẹ́ alágbára Filistini, ẹ ṣe bí ọkùnrin, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin yóò di ẹrú àwọn Heberu, bí wọ́n ti jẹ́ sí i yín. Ẹ jẹ́ alágbára ọkùnrin, kí ẹ sì jagun!”

  20. 1 Samuẹli 4:10nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà àwọn Filistini jà, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn Israẹli olúkúlùkù sì sá padà sínú àgọ́ rẹ̀, wọ́n pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, àwọn ará Israẹli tí ó kú sí ogun sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) àwọn ọmọ-ogun orí ilẹ̀.

  21. 1 Samuẹli 4:11nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Wọ́n gba àpótí ẹ̀rí Olúwa, àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì sì kú, Hofini àti Finehasi.

  22. 1 Samuẹli 4:12nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Lọ́jọ́ kan náà tí ará Benjamini kan sá wá láti ojú ogun tí ó sì lọ sí Ṣilo, aṣọ rẹ̀ sì fàya pẹ̀lú eruku lórí rẹ̀.

  23. 1 Samuẹli 4:13nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ó sì dé, Eli sì jókòó sórí àga rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ó ń wò, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí ọkùnrin náà wọ ìlú tí ó sì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, gbogbo ìlú bẹ̀rẹ̀ sí sọkún.

  24. 1 Samuẹli 4:14nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Eli gbọ́ ìró ohùn ẹkún náà ó sì béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ ariwo yìí?” Ọkùnrin náà sì sáré tọ Eli wá

  25. 1 Samuẹli 4:15nǹkan bí 1141 ṣáájú Kristi

    Eli sì di ẹni méjìdínlọ́gọ́run (98) ọdún, tí ojú rẹ̀ di bàìbàì, kò sì ríran mọ́.