Fò sí àkóónú

circa 1050–1010 BC

Samuel & King Saul

Israel demands a king; Samuel anoints Saul, whose disobedience leads to his rejection as God chooses a man after his own heart.

810 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. 1 Samuẹli 1:26nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Hana sì wí pé, “Olúwa mi, bí ọkàn rẹ ti wà láààyè, Olúwa mi, èmi ni obìnrin náà tí ó dúró lẹ́bàá ọ̀dọ̀ rẹ níhìn-ín tí ń tọrọ lọ́dọ̀ Olúwa.

  2. 1 Samuẹli 1:27nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Ọmọ yìí ni mo ń tọrọ; Olúwa sì fi ìdáhùn ìbéèrè tí mo béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ fún mi.

  3. 1 Samuẹli 1:28nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà pẹ̀lú, èmi fi í fún Olúwa; ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀: nítorí tí mo ti béèrè rẹ̀ fún Olúwa.” Wọn si wólẹ̀ sin Olúwa níbẹ̀.

  4. 1 Samuẹli 2:1nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Hana sì gbàdúrà pé, “Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa; ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa. Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀.

  5. 1 Samuẹli 2:2nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa; kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ; kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.

  6. 1 Samuẹli 2:3nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    “Má ṣe halẹ̀; má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.

  7. 1 Samuẹli 2:4nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    “Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́, àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.

  8. 1 Samuẹli 2:5nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe, àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní. Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje. Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára.

  9. 1 Samuẹli 2:6nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    “Olúwa pa ó sì sọ di ààyè; ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde.

  10. 1 Samuẹli 2:7nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀; ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.

  11. 1 Samuẹli 2:8nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo, “Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti Olúwa ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn.

  12. 1 Samuẹli 2:9nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́, àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn. “Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.

  13. 1 Samuẹli 2:10nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú; láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn; Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé. “Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀, yóò si gbé ìwo ẹni àmì òróró rẹ̀ sókè.”

  14. 1 Samuẹli 2:11nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Elkana sì lọ sí Rama, sí ilé rẹ̀, ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Olúwa níwájú Eli àlùfáà.

  15. 1 Samuẹli 2:12nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Eli sì jẹ́ ọmọ Beliali; wọn kò mọ Olúwa.

  16. 1 Samuẹli 2:13nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀.

  17. 1 Samuẹli 2:14nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí àgé tàbí ọpọ́n, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Israẹli tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣilo.

  18. 1 Samuẹli 2:15nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfáà; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò ṣe tútù.”

  19. 1 Samuẹli 2:16nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́,” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.”

  20. 1 Samuẹli 2:17nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì tóbi gidigidi níwájú Olúwa: nítorí tí àwọn ènìyàn kórìíra ẹbọ Olúwa.

  21. 1 Samuẹli 2:18nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n Samuẹli ń ṣe ìránṣẹ́ níwájú Olúwa, ọmọdé, ti a wọ̀ ní efodu ọ̀gbọ̀.

  22. 1 Samuẹli 2:19nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mú wá fún un lọ́dọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún.

  23. 1 Samuẹli 2:20nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Eli súre fún Elkana àti aya rẹ̀ pé, “Kí Olúwa fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún Olúwa.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn.

  24. 1 Samuẹli 2:21nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Olúwa si bojú wo Hana, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Samuẹli ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú Olúwa.

  25. 1 Samuẹli 2:22nǹkan bí 1165 ṣáájú Kristi

    Eli sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Israẹli; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ.