Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Galatia 4:25nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Hagari yìí ni òkè Sinai Arabia, tí ó sì dúró fún Jerusalẹmu tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.

  2. Galatia 4:26nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa.

  3. Galatia 4:27nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí a ti kọ ọ́ pé, “Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn tí kò bímọ, bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀ yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”

  4. Galatia 4:28nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Isaaki.

  5. Galatia 4:29nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsin yìí.

  6. Galatia 4:30nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ha ti wí, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira obìnrin jogún pọ̀.”

  7. Galatia 4:31nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ará, àwa kì í ṣe ọmọ ẹrúbìnrin bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin.

  8. Galatia 5:1nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin nínú òmìnira náà èyí tí Kristi fi sọ wá di òmìnira, kí ẹ má sì ṣe tún fi ọrùn bọ̀ àjàgà ẹrú mọ́.

  9. Galatia 5:2nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Kíyèsi i, èmi Paulu ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà abẹ́, Kristi kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun.

  10. Galatia 5:3nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbèsè láti pa gbogbo òfin mọ́.

  11. Galatia 5:4nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́.

  12. Galatia 5:5nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo.

  13. Galatia 5:6nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.

  14. Galatia 5:7nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára. Ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí òtítọ́?

  15. Galatia 5:8nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá.

  16. Galatia 5:9nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú.

  17. Galatia 5:10nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́.

  18. Galatia 5:11nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n, ará, bí èmi bá ń wàásù ìkọlà síbẹ̀, kín ni ìdí tí a fi ń ṣe inúnibíni sí mi síbẹ̀? Ǹjẹ́ ìkọ̀sẹ̀ àgbélébùú ti kúrò.

  19. Galatia 5:12nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Èmi ìbá fẹ́ kí àwọn tí ń yọ yín lẹ́nu tilẹ̀ gé ẹ̀yà ara wọn kan kúrò.

  20. Galatia 5:13nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí a ti pè yín sí òmìnira, ará kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín bí àǹfààní sípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejì yín.

  21. Galatia 5:14nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”

  22. Galatia 5:15nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń bu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín run, ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run.

  23. Galatia 5:16nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ mo ní, ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ.

  24. Galatia 5:17nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara, àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́.

  25. Galatia 5:18nǹkan bí 58 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mí ṣamọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin.