Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Johanu 3:2nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa ń ṣe nísinsin yìí, a kò ì tí i fihàn bí àwa ó ti rí: àwa mọ̀ pé, nígbà tí òun ba farahàn, àwa yóò dàbí rẹ̀; nítorí àwa yóò rí i, àní bí òun tí rí.

  2. 1 Johanu 3:3nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Olúkúlùkù ẹni tí ó ba sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀, ń wẹ ara rẹ̀ mọ́, àní bí òun ti mọ́.

  3. 1 Johanu 3:4nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ó ń rú òfin pẹ̀lú, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ni rírú òfin.

  4. 1 Johanu 3:5nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òun farahàn láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò; ẹ̀ṣẹ̀ kò sì ṣí nínú rẹ̀.

  5. 1 Johanu 3:6nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnikẹ́ni tí ó ba ń gbé inú rẹ̀ kì í dẹ́ṣẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń dẹ́ṣẹ̀ kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n.

  6. 1 Johanu 3:7nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín, ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo.

  7. 1 Johanu 3:8nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó lè pa iṣẹ́ èṣù run.

  8. 1 Johanu 3:9nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀; nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀, kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i.

  9. 1 Johanu 3:10nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ èṣù; ẹnikẹ́ni tí kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run.

  10. 1 Johanu 3:11nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa.

  11. 1 Johanu 3:12nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Kì í ṣe bí Kaini, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀. Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á? Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo.

  12. 1 Johanu 3:13nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Kì ẹnu má ṣe yà yín, ẹ̀yin ará mi, bí ayé bá kórìíra yín.

  13. 1 Johanu 3:14nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Àwa mọ̀ pé àwa tí rékọjá láti inú ikú sínú ìyè, nítorí tí àwa fẹ́ràn àwọn ará. Ẹni tí kò ba ni ìfẹ́, ó ń gbé inú ikú.

  14. 1 Johanu 3:15nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni, ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí ó ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀.

  15. 1 Johanu 3:16nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará.

  16. 1 Johanu 3:17nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀?

  17. 1 Johanu 3:18nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.

  18. 1 Johanu 3:19nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì fi ọkàn ara wa balẹ̀ níwájú rẹ̀.

  19. 1 Johanu 3:20nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Nínú ohunkóhun tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi; nítorí pé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.

  20. 1 Johanu 3:21nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Olùfẹ́, bí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, ǹjẹ́ àwa ni ìgboyà níwájú Ọlọ́run?

  21. 1 Johanu 3:22nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Àti ohunkóhun tí àwa bá béèrè, ni àwa ń rí gbà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí àwa ń pa òfin rẹ̀ mọ́, àwa sì ń ṣe àwọn nǹkan tí ó dára lójú rẹ̀.

  22. 1 Johanu 3:23nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Èyí sì ni òfin rẹ̀, pé kí àwa gba orúkọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, kí a sì fẹ́ràn ara wá gẹ́gẹ́ bí ó tí fi òfin fún wa.

  23. 1 Johanu 3:24nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ó bá sì pa òfin rẹ̀ mọ́ ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú rẹ̀. Àti nípa èyí ni àwa mọ̀ pé ó ń gbé inú wa, nípa Ẹ̀mí tí ó fi fún wa.

  24. 1 Johanu 4:1nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run, nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé.

  25. 1 Johanu 4:2nǹkan bí 90 lẹ́yìn Kristi

    Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run. Gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni.