Fò sí àkóónú

Galilee

63 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Gilgal

32.7000, 35.3000 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Galilee

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili àti Judea sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

  2. Níkẹyìn Herodia rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Herodu, òun sì pèsè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn ènìyàn pàtàkì ní Galili.

  3. Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n gba Galili kọjá. Níbẹ̀ ni Jesu ti gbìyànjú láti yẹra kí ó bá à lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí ó lè ráàyè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i.

  4. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, èmi yóò síwájú yin lọ sí Galili.”

  5. Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Galili máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.

  6. Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Peteru wí pé, ‘Òun ti ń lọ síwájú yín sí Galili. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’ ”

  7. Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán angẹli Gabrieli sí ìlú kan ní Galili, tí à ń pè ní Nasareti,

  8. Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti Nasareti ni Galili, sí ìlú Dafidi ní Judea, tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé Dafidi ní í ṣe,

  9. Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Galili, sí Nasareti ìlú wọn.

  10. Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene,

  11. Jesu sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Galili, òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.

  12. Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kapernaumu, ìlú kan ní Galili, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi.

  13. Ní ọjọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisi àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Galili gbogbo, àti Judea, àti Jerusalẹmu wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá.

  14. Wọ́n sì gúnlẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Gadara, tí ó kọjú sí Galili.

  15. Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu, ó kọjá láàrín Samaria Galili.

  16. Wọ́n sì túbọ̀ tẹnumọ́ ọn pé, “Ó ń ru ènìyàn sókè, ó ń kọ́ni káàkiri gbogbo Judea, ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili títí ó fi dé ìhín yìí!”

  17. Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili wá, wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí.

  18. Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Galili wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsi ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀.

  19. Kò sí níhìn-ín yìí, ṣùgbọ́n ó jíǹde; ẹ rántí bí ó ti wí fún yín nígbà tí ó wà ní Galili.

  20. Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

  21. Ní ọjọ́ kẹta, wọn ń ṣe ìgbéyàwó kan ní Kana ti Galili. Ìyá Jesu sì wà níbẹ̀.

  22. Èyí jẹ́ àkọ́ṣe iṣẹ́ àmì, tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.

  23. Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili.

  24. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì ó sì ti ibẹ̀ kúrò, ó lọ sí Galili.

  25. Nítorí náà nígbà tí ó dé Galili, àwọn ará Galili gbà á, nítorí ti wọ́n ti rí ohun gbogbo tí ó ṣe ní Jerusalẹmu nígbà àjọ ìrékọjá; nítorí àwọn tìkára wọn lọ sí àjọ pẹ̀lú.