Fò sí àkóónú

Judah

244 ẹsẹ · 20 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Judas, Juda

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Judah

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ní ọdún méjìlá Joramu ọmọkùnrin Ahabu ọba Israẹli, Ahasiah ọmọkùnrin Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀.

  2. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Joramu padà sí Jesreeli láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí ará Siria ti jẹ ní yà lórí rẹ̀ ní Ramoti ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Hasaeli ọba Aramu. Nígbà náà Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jesreeli láti lọ wo Joramu ọmọ Ahabu nítorí tí ó fi ara pa.

  3. Nígbà náà Jehu wọ inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì gùn ún lọ sí Jesreeli, nítorí Joramu ń sinmi níbẹ̀ àti Ahasiah ọba Juda sì sọ̀kalẹ̀ láti wá wò Joramu.

  4. “Fi ìwọ̀ kọ́ kẹ̀kẹ́ ogun mi.” Joramu pa á láṣẹ. Àti nígbà tí a fi kọ́, Joramu ọba Israẹli àti Ahasiah ọba Juda, gun kẹ̀kẹ́ lọ, olúkúlùkù nínú kẹ̀kẹ́ ogun tirẹ̀, láti lọ bá Jehu. Wọ́n bá a pàdé ní ibi oko tí ó ti jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli.

  5. Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀.

  6. (Ní ọdún kọkànlá ti Joramu ọmọ Ahabu, Ahasiah ti di ọba Juda.)

  7. Jehu pàdé díẹ̀ lára àwọn ìbátan Ahasiah ọba Juda, ó sì béèrè, “Ta ni ẹ̀yin ń ṣe?” Wọ́n wí pé, “Àwa jẹ́ ìbátan Ahasiah, àwa sì ti wá láti kí ìdílé ọba àti ti màmá ayaba.”

  8. Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Juda mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀ Jehoṣafati, Jehoramu àti Ahasiah, àwọn ọba Juda, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti ní ti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hasaeli; ọba Siria, tí ó sì fà padà kúrò ní Jerusalẹmu.

  9. Pẹ̀lú ìyókù ìṣe Joaṣi, àti ohun gbogbo tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?

  10. Ní ọdún kẹtàlélógún ti Joaṣi ọmọ ọba Ahasiah ti Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tàdínlógún.

  11. Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Joaṣi ọba Juda, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi di ọba Israẹli ní Samaria ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́rìndínlógún.

  12. Fún ti ìyókù iṣẹ́ Jehoaṣi fún ìgbà tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe, pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀ pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?

  13. Ní ọdún kejì tí Jehoaṣi ọmọ Joahasi ọba Israẹli, Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba.

  14. Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì sí Amasiah ọba Juda: “Òṣùṣú kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí kedari ní Lebanoni, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó.’ Nígbà náà ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tinú igbó ní Lebanoni wá pẹ̀lú ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ òṣùṣú náà mọ́lẹ̀.

  15. Ìwọ ti ṣẹ́gun Edomu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n, nísinsin yìí ìwọ ṣe ìgbéraga. Ògo nínú ìṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n dúró nílé! Kí ni ó dé tí o fi ń wá wàhálà tí o sì fa ìṣubú rẹ àti ti Juda pẹ̀lú?”

  16. Bí ó ti wù kí ó rí Amasiah kò ní tẹ́tí, bẹ́ẹ̀ ni Jehoaṣi ọba Israẹli sì dojúkọ ọ́. Òun àti Amasiah ọba Juda kọjú sí ara wọn ní Beti-Ṣemeṣi ní Juda.

  17. A kó ipa ọ̀nà Juda nípasẹ̀ Israẹli, gbogbo àwọn ọkùnrin sì sálọ sí ilé e rẹ̀.

  18. Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi, ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà, Jehoaṣi lọ sí Jerusalẹmu, ó sì lọ wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Efraimu sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ irinwó (400) ìgbọ̀nwọ́.

  19. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jehoaṣi, gbogbo ohun tí ó ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?

  20. Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli.

  21. Fún ti ìyókù iṣẹ́ rẹ̀ nígbà ìjọba Amasiah, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?

  22. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn Juda mú Asariah tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Wọ́n sì ṣe é ní ọba ní ìrọ́pò baba rẹ̀ Amasiah.

  23. Òun ni ẹni tí ó tún Elati kọ́, ó sì dá a padà sí Juda lẹ́yìn tí Amasiah ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.

  24. Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún tí Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda, Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ọba Israẹli di ọba ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún ọ̀kànlélógójì ọdún.

  25. Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jeroboamu, gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo àwọn agbára rẹ, bí ó ti jagun sí, àti bí ó ti gba Damasku àti Hamati, tí í ṣe ti Juda, padà fún Israẹli, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?