Fò sí àkóónú

Jesus

3,872 ẹsẹ · 6 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń bẹ ni àárín ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn wọn, ‘tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè.’ ‘Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.’ ”

  2. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì keje, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ̀n ààbọ̀ wákàtí kan.

  3. Ó sì fi ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láé búra, ẹni tí o dá ọ̀run, àti ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀, ayé ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀ pé, “Kí yóò si ìjáfara mọ́.

  4. Ohùn náà tí mo gbọ́ láti ọ̀run tún ń ba mi sọ̀rọ̀, ó sì wí pé, “Lọ, gba ìwé tí o ṣí lọ́wọ́ angẹli tí o dúró lórí Òkun àti lórí ilẹ̀.”

  5. Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèje, wọn ó sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó lé ọgọ́ta (1,260) nínú aṣọ ọ̀fọ̀.”

  6. Òkú wọn yóò sì wà ni ìgboro ìlú ńlá náà tí a ń pè ní Sodomu àti Ejibiti nípa ti ẹ̀mí, níbi tí a gbé kan Olúwa wọ́n mọ́ àgbélébùú.

  7. Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé, “Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀; òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”

  8. wí pé: “Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè, tí ń bẹ, tí ó sì ti wà, nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀, ìwọ sì ti jẹ ọba.

  9. Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ̀ ti dé, àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́, àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì, àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀, àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá; àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.”

  10. Ó sì lóyún, ó sì kígbe ni ìrọbí, ó sì wà ni ìrora àti bímọ.

  11. Ìrù rẹ̀ sì wọ́ ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀ ní ojú ọ̀run, ó sì jù wọ́n sí ilẹ̀ ayé, dragoni náà sì dúró níwájú obìnrin náà tí ó fẹ́ bímọ, pé nígbà tí o bá bí i, kí òun lè pa ọmọ rẹ̀ jẹ.

  12. Ó sì bi ọmọkùnrin kan tí yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, a sì gba ọmọ rẹ̀ lọ sókè sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti sí orí ìtẹ́ rẹ̀.

  13. Mo sì gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run, wí pè: “Nígbà yìí ni ìgbàlà dé, àti agbára, àti ìjọba Ọlọ́run wá, àti ọlá àti Kristi rẹ̀. Nítorí a tí le olùfisùn àwọn arákùnrin wa jáde, tí o ń fi wọ́n sùn níwájú Ọlọ́run wa lọ́sàn án àti lóru.

  14. Wọ́n sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn náà, àti nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn, wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn àní títí dé ikú.

  15. Nígbà tí dragoni náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ̀ ayé, ó ṣe inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà.

  16. Dragoni náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú-ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọ́n ń pa òfin Ọlọ́run mọ̀, tí wọn sì di ẹ̀rí Jesu mú, Ó sì dúró lórí iyanrìn Òkun.

  17. Ó sì ya ẹnu rẹ̀ ni ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rẹ̀, àti sí àgọ́ rẹ̀, àti sí àwọn tí ń gbé ọ̀run.

  18. Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlùkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

  19. Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.

  20. Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí, nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.

  21. Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn.

  22. Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.

  23. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.” Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”

  24. Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà ẹnìkan jókòó tí o dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀.

  25. Angẹli mìíràn sì tí inú tẹmpili jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.”