God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Àwọn ará Israẹli rìn ní aginjù fún ogójì ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni Ejibiti fi kú, nítorí wọn kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa. Nítorí Olúwa ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fi fun wa, ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin.
Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé àwọn ọmọ wọn dìde dípò wọn, àwọn wọ̀nyí sì ni Joṣua kọ ní ilà. Wọ́n wà ní aláìkọlà nítorí a kò tí ì kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà.
Nígbà náà ní Olúwa wí fún Joṣua pé, “Ní òní ni mo yí ẹ̀gàn Ejibiti kúrò ní orí yín.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Gilgali títí ó fi di òní yìí.
“Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun Olúwa ni mo wá nísinsin yìí.” Nígbà náà ni Joṣua sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, “Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?”
Olórí ogun Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé ibi tí ìwọ dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀.
Nígbà náà ni Olúwa wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo ti fi Jeriko lé ọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọba rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ọmọ Nuni pe àwọn àlùfáà ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa náà kí àwọn àlùfáà méje tí ó ru fèrè ìwo wà ní iwájú u rẹ̀.”
Ó sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ lọ, kí ẹ sì yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ tí ó hámọ́ra kọjá ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa.”
Nígbà tí Joṣua ti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ tán, àwọn àlùfáà méje tí wọ́n gbé fèrè méje ní iwájú Olúwa kọjá sí iwájú, wọ́n sì fọn fèrè wọn, àpótí ẹ̀rí Olúwa sì tẹ̀lé wọn.
Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí àpótí ẹ̀rí Olúwa yí ìlú náà ká, ó sì yí i ká lẹ́ẹ̀kan. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà padà sí ibùdó, wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún alẹ́ náà.
Joṣua sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa.
Àwọn àlùfáà méje tí ó gbé ìpè ìwo àgbò méje ń lọ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n sì ń fọ́n àwọn ìpè: àwọn tí ó hámọ́ra ogun ń lọ níwájú u wọn; àwọn ọmọ tó wà lẹ́yìn sì ń tọ àpótí ẹ̀rí Olúwa lẹ́yìn, àwọn àlùfáà sì ń fọn ìpè bí wọ́n ti ń lọ.
Ní ìgbà keje, nígbà tí àwọn àlùfáà fọn fèrè, Joṣua pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ hó! Nítorí pé Olúwa ti fún un yín ní ìlú náà.
Ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà níbẹ̀ ni yóò jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ fún Olúwa. Rahabu tí ó jẹ́ panṣágà nìkan àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ ni a ó dá sí; nítorí tí ó pa àwọn ayọ́lẹ̀wò tí á rán mọ́.
Gbogbo fàdákà àti wúrà àti ohun èlò idẹ àti irin jẹ́ mímọ́ fún Olúwa, wọ́n yóò wá sínú ìṣúra Olúwa.”
Nígbà náà ni wọ́n sun gbogbo ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú u rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi fàdákà, wúrà ohun èlò idẹ àti irin sínú ìṣúra ilé Olúwa.
Ní àkókò náà Joṣua sì búra pé, “Ègún ni fún ẹni náà níwájú Olúwa tí yóò dìde, tí yóò sì tún ìlú Jeriko kọ́: “Pẹ̀lú ikú àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ni yóò fi pilẹ̀ rẹ̀; ikú àbíkẹ́yìn rẹ̀ ní yóò fi gbé ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ ró.”
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wà pẹ̀lú Joṣua; òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.
Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀yà Juda, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ará Israẹli.
Joṣua sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa títí di àṣálẹ́. Àwọn àgbà Israẹli sì ṣe bákan náà, wọ́n ku eruku sí orí wọn.
Joṣua sì wí pé, “Háà, Olúwa Olódùmarè, nítorí kín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá Jordani, láti fi wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́, láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdìkejì Jordani?
Olúwa, kín ni èmi yóò sọ nísinsin yìí tí Israẹli sì ti sá níwájú ọ̀tá a rẹ̀?
Àwọn Kenaani àti àwọn ènìyàn ìlú tí ó kù náà yóò gbọ́ èyí, wọn yóò sì yí wa ká, wọn yóò sì ké orúkọ wa kúrò ní ayé. Kí ni ìwọ ó ha ṣe fún orúkọ ńlá à rẹ?”
Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojúbolẹ̀?
Israẹli ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn.