Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ búra fún mi ní ti Olúwa pé ẹ̀yin yóò ṣe àánú fún ìdílé mi, nítorí pé mo ti ṣe yín ní oore. Ẹ̀yin yóò fún mi ní àmì tó dájú:

  2. “Ẹ̀mí wa fún ẹ̀mí in yín!” àwọn ọkùnrin náà mú dá a lójú. “Tí ìwọ kò bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò sì fi òtítọ́ àti àánú bá ọ lò nígbà tí Olúwa bá fún wa ní ilẹ̀ náà.”

  3. Wọ́n sì sọ fún Joṣua, “Nítòótọ́ ni Olúwa tí fi gbogbo ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́; gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà ni ìbẹ̀rùbojo ti mú nítorí i wa.”

  4. Wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Nígbà tí ẹ bá rí àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín, tí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi rù ú, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sí kúrò ní ipò yín, ẹ̀yin yóò sì máa tẹ̀lé e.

  5. Joṣua sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́, nítorí ní ọ̀la, Olúwa yóò ṣe ohun ìyanu ní àárín yín.”

  6. Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Israẹli, kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mose.

  7. Joṣua sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ súnmọ́ ibí kí ẹ̀yin kí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín.

  8. Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárín yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, Hifi, Peresi, Girgaṣi, Amori àti Jebusi jáde níwájú u yín.

  9. Àpótí májẹ̀mú Olúwa gbogbo ayé ń gòkè lọ sí Jordani ṣáájú u yín.

  10. Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí Olúwa, Olúwa gbogbo ayé bá ti ẹsẹ̀ bọ odò Jordani, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbá jọ bí òkìtì kan.”

  11. Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa sì dúró ṣinṣin lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárín Jordani, nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi rékọjá nínú odò Jordani lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

  12. Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè náà kọjá nínú odò Jordani tan, Olúwa sọ fún Joṣua pé,

  13. ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín sí àárín odò Jordani. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli,

  14. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jordani kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Nígbà tí a rékọjá a Jordani, a gé omi Jordani kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli láéláé.”

  15. Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe bí Joṣua ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n gbé òkúta méjìlá láti àárín odò Jordani gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli, bí Olúwa ti sọ fún Joṣua; wọ́n sì rù wọ́n kọjá lọ sí ibùdó, ní ibi tí wọ́n ti gbé wọn kalẹ̀.

  16. Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárín Jordani títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pàṣẹ fún Joṣua fi di ṣíṣe nípasẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún Joṣua. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá,

  17. bí gbogbo wọn sì ti rékọjá tán, ni àpótí ẹ̀rí Olúwa àti àwọn àlùfáà wá sí òdìkejì. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń wò wọ́n.

  18. Àwọn bí ọ̀kẹ́ méjì (40,000) tó ti múra fún ogun rékọjá lọ ní iwájú Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko láti jagun.

  19. Ní ọjọ́ náà ni Olúwa gbé Joṣua ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì bẹ̀rù u rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé e wọn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti bẹ̀rù Mose.

  20. Olúwa sì sọ fún Joṣua pé,

  21. Àwọn àlùfáà náà jáde láti inú odò pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa ni orí wọn. Bí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ ẹ wọn tẹ orí ilẹ̀ gbígbẹ ni omi Jordani náà padà sí ààyè e rẹ̀, o sì kún wọ bèbè bí i ti àtẹ̀yìnwá.

  22. Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jordani gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jordani gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá.

  23. Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo.”

  24. Nígbà tí gbogbo àwọn ọba Amori ti ìlà-oòrùn Jordani àti gbogbo àwọn ọba Kenaani tí ń bẹ létí òkun gbọ́ bí Olúwa ti mú Jordani gbẹ ní iwájú àwọn ọmọ Israẹli títí ti a fi kọjá, ọkàn wọn pami, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ìgboyà mọ́ láti dojúkọ àwọn ọmọ Israẹli.

  25. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Joṣua pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ kí o sì kọ àwọn ọmọ Israẹli ní ilà ní ìgbà ẹ̀ẹ̀kejì.”