God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,” ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n? Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?
Àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínú yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi, má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun.
Ògo Ọlọ́run ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́; láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba.
Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ.
Bí tafàtafà ti ń ṣe ni léṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ẹni tí ó gba aṣiwèrè ṣíṣẹ́ tàbí ẹni tí ń kọjá lọ.
Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára.
Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀.
Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, Olúwa jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.
Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù Olúwa wà láìléwu.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóso, ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.
Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì.
Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀? Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀? Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ? Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀? Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀? Sọ fún mi bí o bá mọ̀.
“Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù; òun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn.
Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.
“Ohun méjì ni mo ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, Olúwa; má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú.
Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ kí ń sì wí pé, ‘Ta ni Olúwa?’ Tàbí kí ń di òtòṣì kí ń sì jalè kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.
Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.
Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà! Ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn.
Ènìyàn kò le è ṣe ohunkóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run.
Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn.
Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, síbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.
Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́.
Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni.