Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run síjú àánú wo ohun tí o ṣe.

  2. Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn.

  3. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́dàá ohun gbogbo.

  4. Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ. Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.

  5. Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà, tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.

  6. Nísinsin yìí, òpin gbogbo ọ̀rọ̀ tí a gbọ́ ni pé, bẹ̀rù Ọlọ́run, kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́, nítorí èyí ni ojúṣe gbogbo ènìyàn.

  7. Nítorí Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ olúkúlùkù iṣẹ́ àti ohun ìkọ̀kọ̀, kì bá à ṣe rere kì bá à ṣe búburú.

  8. Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé! Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀: “Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà, ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.

  9. Màlúù mọ olówó rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀, ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀, òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”

  10. Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù, ìran àwọn aṣebi, àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́! Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀ wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli, wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.

  11. Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà, a ò bá ti rí bí Sodomu, a ò bá sì ti dàbí Gomorra.

  12. Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin aláṣẹ Sodomu, tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn Gomorra!

  13. “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí. “Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa, Èmi kò ní inú dídùn nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti òbúkọ.

  14. Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi, ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín, gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?

  15. Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́! Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi, oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ, Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.

  16. Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àjọ̀dún tí a yàn, ni ọkàn mi kórìíra. Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn, Ó sú mi láti fi ara dà wọ́n.

  17. Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà, Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín, kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà, Èmi kò ni tẹ́tí sí i. “Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.

  18. “Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,” ni Olúwa wí. “Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn, wọn ó sì funfun bí i yìnyín, bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀, wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú.

  19. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀, idà ni a ó fi pa yín run.” Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́.

  20. Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé: “Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.

  21. Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.

  22. Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́, àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”

  23. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó parun. Àwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.

  24. Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́ òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.

  25. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.