God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ìbẹ̀rù Olúwa jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú.
Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
Ojú Olúwa wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.
Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ ẹ lọ́rùn.
Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.
Ikú àti ìparun ṣí sílẹ̀ níwájú Olúwa, mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.
Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù Olúwa sì wà ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.
Olúwa fa ilé onígbèéraga ya lulẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó onírẹ̀lẹ̀ mọ́ láìyẹ̀.
Olúwa kórìíra èrò ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹni pípé.
Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburú ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.
Ìbẹ̀rù Olúwa kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n, ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.
Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.
Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́, èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.
Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́ kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.
Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀ mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.
Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.
Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn, yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà.
Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.
Òdínwọ̀n àti òsùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa; gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre, ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ, ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.
Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà, ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.
Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, Olúwa kórìíra méjèèjì.
Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni; olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.