Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo na ọwọ́ sí wọn,

  2. níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi, tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi,

  3. “Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn; wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.

  4. Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀ tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù Olúwa.

  5. Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi,

  6. ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láìsí ìbẹ̀rù ìpalára.”

  7. Ọmọ mi, bí ìwọ bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ sí inú rẹ,

  8. Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.

  9. Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.

  10. Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,

  11. Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.

  12. ẹni tí ó ti kọ ọkọ àkọ́fẹ́ ìgbà èwe rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé májẹ̀mú tí ó ti dá níwájú Ọlọ́run rẹ̀.

  13. Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi. Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.

  14. Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.

  15. Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ.

  16. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù Olúwa kí o sì kórìíra ibi.

  17. Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún Olúwa, pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ,

  18. Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olúwa má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,

  19. nítorí Olúwa a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.

  20. Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

  21. Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura, òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

  22. Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á; àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.

  23. Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn;

  24. nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà, àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.

  25. Nítorí Olúwa yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ, kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.