Fò sí àkóónú

Daniel

72 ẹsẹ

A tún mọ̀ ọ́n sí: Belteshazzar

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Daniel

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Mo gbé àṣẹ kan jáde wí pé, ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Daniẹli.

  2. Ó ń yọ ni, ó sì ń gbani là;

  3. Daniẹli sì ṣe rere ní àkókò ìjọba Dariusi àti àkókò ìjọba Kirusi ti Persia.

  4. Ní ọdún àkọ́kọ́ Belṣassari ọba Babeli, Daniẹli lá àlá kan, ìran náà sì wá sí ọkàn an rẹ̀ bí ó ṣe sùn sórí ibùsùn un rẹ̀, ó sì kọ àlá náà sílẹ̀.

  5. Daniẹli sọ pé, “Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi Òkun ńlá sókè.

  6. “Ọkàn èmi Daniẹli, dàrú, ìran tí ó wá sọ́kàn mi dẹ́rùbà mí.

  7. “Báyìí ni àlá náà ṣe parí, ọkàn èmi Daniẹli sì dàrú gidigidi, nítorí èrò ọkàn mi yìí, ojú mi sì yípadà ṣùgbọ́n mo pa ọ̀ràn náà mọ́ ní ọkàn mi.”

  8. Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Belṣassari ọba, èmi Daniẹli rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀.

  9. Nígbà tí èmi Daniẹli, ń wo ìran náà, mo sì ń fẹ́ kí ó yé mi, ẹnìkan tí ó sì dúró níwájú mi.

  10. Èmi Daniẹli sì ṣe àárẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan. Nígbà náà, mo dìde, mo sì ń bá iṣẹ́ ọba lọ. Ìran náà sì bà mí lẹ́rù, kò sì yé mi.

  11. Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, èmi Daniẹli fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí wòlíì Jeremiah, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jerusalẹmu yóò fi wà ní ahoro.

  12. Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, “Daniẹli, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye.

  13. Ní ọdún kẹta Kirusi ọba Persia, a fi ìran kan hàn Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belteṣassari). Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran.

  14. Ní àsìkò náà, èmi Daniẹli ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta.

  15. Èmi Daniẹli, ni ẹnìkan tí ó rí ìran náà, àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú u mi, wọn kò rí i, ṣùgbọ́n ìpayà ńlá dà bò wọ́n, wọ́n sálọ wọ́n sì fi ara pamọ́.

  16. Ó sọ pé, “Daniẹli ẹni tí a yàn fẹ́ gidigidi gba ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ yìí yẹ̀ wò dáradára, kí o sì dìde, nítorí tí a rán mi sí ọ.” Bí ó ṣe sọ èyí fún mi, mo dìde ní ìwárìrì.

  17. Nígbà náà ni ó tẹ̀síwájú, pé, “Má ṣe bẹ̀rù Daniẹli. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fi ọkàn rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì wá nítorí ọ̀rọ̀ náà.

  18. Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”

  19. Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè.

  20. Ó sì dáhùn pé, “Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, Daniẹli nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dì í di ìgbà ìkẹyìn.

  21. “Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ‘ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ,’ tí ó bá dúró ní ibi mímọ́ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e),

  22. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró níbí tí kò yẹ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e), nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè.