Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Interpreter

16 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ó sọ fún wọn pé kí wọn béèrè fún àánú Ọlọ́run, Olúwa ọ̀run, nítorí àṣírí yìí, kí Daniẹli pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má ba ṣègbé pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n Babeli yòókù, tí ó wà ní Babeli.

  2. Ní òru, àṣírí náà hàn sí Daniẹli ní ojú ìran. Nígbà náà ni Daniẹli fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run

  3. Daniẹli wí pé: “Ọpẹ́ ni fún orúkọ Ọlọ́run láé àti láéláé; tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára.

  4. Ó yí ìgbà àti àkókò padà; ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò. Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.

  5. Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn; ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà.

  6. Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi: ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

  7. Nígbà náà ni Daniẹli tọ́ Arioku lọ, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Babeli run, Daniẹli wí fún un pé, “Má ṣe pa àwọn amòye Babeli run. Mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, èmi yóò sísọ ìtumọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”

  8. Lẹ́sẹ̀kan náà, Arioku yára mú Daniẹli lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, “Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Juda, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”

  9. Ọba béèrè lọ́wọ́ Daniẹli ẹni tí a tún ń pè ní Belṣassari pé, “Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi?”

  10. Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àṣírí tí ọba béèrè fún

  11. ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn. Ó ti fihan ọba Nebukadnessari, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:

  12. “Ọba, bí ìwọ ṣe sùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àṣírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ.

  13. Ṣùgbọ́n fún èmi, a fi àṣírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀.

  14. Ǹjẹ́ èéha ti ṣe, kín ni àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin péjọpọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Saamu kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan àti ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró.

  15. Bí ẹnìkan bá fi èdè fọ̀, kí ó jẹ ènìyàn méjì, tàbí bí ó pọ̀ tán, kí ó jẹ́ mẹ́ta, kí ó sọ̀rọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, kí ẹnìkan sì túmọ̀ rẹ̀.

  16. Ṣùgbọ́n bí kò bá sí ògbufọ̀, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ nínú ìjọ; sì jẹ́ kí ó máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀.