Skip to content

Arioch

4 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Arioch

  1. Nígbà tí Arioku, olórí àwọn olùṣọ́ ọba, jáde láti lọ pa àwọn amòye Babeli, Daniẹli sọ̀rọ̀ fún un pẹ̀lú ọgbọ́n àti òye.

  2. Ó béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùṣọ́ ọba wí pé, “Èéṣe tí àṣẹ ọba fi yá kánkán bẹ́ẹ̀?” Arioku sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Daniẹli.

  3. Nígbà náà ni Daniẹli tọ́ Arioku lọ, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Babeli run, Daniẹli wí fún un pé, “Má ṣe pa àwọn amòye Babeli run. Mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, èmi yóò sísọ ìtumọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”

  4. Lẹ́sẹ̀kan náà, Arioku yára mú Daniẹli lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, “Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Juda, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”