Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Watchfulness

167 ẹsẹ · 28 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn aláìgbọ́n márùn-ún tí kò ní epo rárá bẹ àwọn ọlọ́gbọ́n pé kí wọn fún àwọn nínú èyí tí wọ́n ní nítorí fìtílà wọn ń kú lọ.

  2. “Ṣùgbọ́n ọkọ ìyàwó dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín èmi kò mọ̀ yín rí.’

  3. “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà. Nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí Ọmọ Ènìyàn yóò dé.

  4. Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ọkàn mi gbọgbẹ́ pẹ̀lú ìbànújẹ́ títí dé ojú ikú, ẹ dúró níhìn-ín yìí, kí ẹ máa ṣọ́nà pẹ̀lú mi.”

  5. Bí ó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ó bá wọn, wọ́n ń sùn. Ó kígbe pé, “Peteru, ẹ̀yin kò tilẹ̀ lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan?

  6. Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì máa gbàdúrà kí ẹ̀yin má ba à bọ́ sínú ìdẹwò. Nítorí ẹ̀mí ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.”

  7. Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ máa kíyèsi ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òsùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n náà ni a ó fi wọ́n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.

  8. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyèsára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú Sinagọgu wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn baálẹ̀ àti níwájú àwọn ọba nítorí orúkọ mi, fún ẹ̀rí fún wọn.

  9. Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìyìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé.

  10. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń fà yín lọ, tí wọ́n bá sì ń fi yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn ṣáájú ohun tí ẹ ó sọ. Ṣùgbọ́n ohun tí bá fi fún yín ní wákàtí náà, òun ni kí ẹ̀yin kí ó wí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń wí, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.

  11. “Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn.

  12. Àwọn ènìyàn yóò kórìíra yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fi ara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.

  13. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró níbí tí kò yẹ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e), nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè.

  14. Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.

  15. Kí ẹni tí ó wà lóko má ṣe padà sẹ́yìn láti wá mú aṣọ rẹ̀.

  16. Ègbé ní fún àwọn tí ó lóyún, àti fún obìnrin tí ń fún ọ́mọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀nyí.

  17. Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé èyí ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù.

  18. Nítorí ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì yóò jẹ́ àkókò ìpọ́njú, irú èyí tí kò ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá Ọlọ́run. Irú rẹ̀ kò sì ni ṣẹlẹ̀ mọ́.

  19. “Àfi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù.

  20. Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kristi wa níbi yìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́.

  21. Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ.

  22. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra. Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó!

  23. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe baba nìkan.

  24. Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró wámú, kí ẹ sì máa gbàdúrà, nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò ná yóò dé.

  25. Ó dà bí ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà rere, ẹni tí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi àṣẹ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe, ó sì fi àṣẹ fún ẹni tó dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà.