Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tyre

113 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli, àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí. Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.

  2. Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi; wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!

  3. Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:

  4. “Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú, ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé; lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin, kí a lè ba à rántí rẹ.”

  5. Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.

  6. Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún Olúwa; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.

  7. gbogbo àwọn ọba Tire àti Sidoni; gbogbo àwọn ọba erékùṣù wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ìkọjá Òkun.

  8. Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Ṣe àjàgà àti ọ̀pá irin fún ara rẹ, kí o sì fiwé ọrùn rẹ.

  9. Kí o rán ọ̀rọ̀ sí ọba ti Edomu, Moabu, Ammoni, Tire àti Sidoni láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Sedekiah ọba Juda.

  10. Nísinsin yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ fún Nebukadnessari ọba Babeli ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀.

  11. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’

  12. “Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tire sọ nípa Jerusalẹmu pé, ‘Háà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’

  13. nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, kíyèsi i, èmí dojúkọ ọ́ ìwọ tire, Èmi yóò sì jẹ́ kí Orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ, gẹ́gẹ́ bí Òkun tí ru sókè.

  14. Wọn yóò wó odi tire lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀, Èmi yóò sì ha erùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta.

  15. Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàrín Òkun, ní Olúwa Olódùmarè wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè.

  16. “Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadnessari ọba Babeli, ọba àwọn ọba, dìde sí Tire pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun.

  17. Yóò sì fi idà sá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkìtì tì ọ́, yóò sì gbé àpáta sókè sí ọ.

  18. Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀.

  19. Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu-ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti ó di fífọ́ pátápátá.

  20. Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀; yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀.

  21. Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun; wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú Òkun.

  22. Èmi yóò sì mú ariwo orin rẹ̀ dákẹ́ àti ìró dùùrù orin rẹ̀ ni a kì yóò gbọ́ mọ́.

  23. Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí Èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Olódùmarè wí.

  24. “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Tire: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú rẹ?

  25. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́.