Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tyre: To be scraped as the top of a rock, and to be a place for the spreading nets

4 ẹsẹ · 47 abala

Àwọn ẹsẹ nípa To be scraped as the top of a rock, and to be a place for the spreading nets

  1. nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí, kíyèsi i, èmí dojúkọ ọ́ ìwọ tire, Èmi yóò sì jẹ́ kí Orílẹ̀-èdè púpọ̀ dìde sí ọ, gẹ́gẹ́ bí Òkun tí ru sókè.

  2. Wọn yóò wó odi tire lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀, Èmi yóò sì ha erùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta.

  3. Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàrín Òkun, ní Olúwa Olódùmarè wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè.

  4. Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí Èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Olódùmarè wí.