Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tyre: The king of Babylon to be rewarded with the spoil of Egypt for his service against
Àwọn ẹsẹ nípa The king of Babylon to be rewarded with the spoil of Egypt for his service against
“Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn.
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀.
Èmi ti fi Ejibiti fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Olódùmarè wí.