Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Mercy of God

102 ẹsẹ · 36 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

  2. Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́ Olúwa ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ,

  3. Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

  4. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

  5. Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa, ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún, fún àánú àti òtítọ́ rẹ.

  6. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára; àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  7. Jẹ́ kí Israẹli wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.

  8. Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.

  9. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”

  10. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  11. Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ, Olúwa, kọ́ mi ní òfin rẹ.

  12. Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa: nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà.

  13. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  14. Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  15. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  16. Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  17. Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  18. Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  19. Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  20. Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  21. Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  22. Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  23. Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  24. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  25. Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.