Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Mercy of God: Is part of his character
Àwọn ẹsẹ nípa Is part of his character
Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́,
Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1,000), ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.”
Wọ́n kọ̀ láti fetísílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárín wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrú wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀,
pẹ̀lúpẹ̀lú, Olúwa, tìrẹ ni àánú; nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.”
Ó sì gbàdúrà sí Olúwa, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, Olúwa, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyí nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítorí èyí ni mo ṣé sálọ sí Tarṣiṣi ní ìṣáájú: nítorí èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà.
Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fun, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan.
Ṣùgbọ́n Ninefe ní jù ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ìlú ńlá náà?”
Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.