Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Mercy of God: Everlasting
Àwọn ẹsẹ nípa Everlasting
Fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára; ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé.
Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un, àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.
Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun; nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀ nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ó sì pa àwọn ọba olókìkí nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Sihoni, ọba àwọn ará Amori nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Àti Ogu, ọba Baṣani; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.