Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Jews

231 ẹsẹ · 158 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn ẹni tí ó ń mọ odi. Àwọn tí ń ru àwọn ohun èlò ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú ọwọ́ kan, wọ́n sì fi ọwọ́ kejì di ohun ìjà mú,

  2. olúkúlùkù àwọn ọ̀mọ̀lé fi idà wọn sí ẹ̀gbẹ́ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ń fọn ìpè dúró pẹ̀lú mi.

  3. Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tókù pé, “Iṣẹ́ náà fẹ̀ ó sì pọ̀, a sì ti jìnnà sí ara wa púpọ̀ lórí odi.

  4. Níbikíbi tí ẹ bá ti gbọ́ ohùn ìpè, ẹ da ara pọ̀ mọ́ wa níbẹ̀. Ọlọ́run wa yóò jà fún wa!”

  5. Bẹ́ẹ̀ ni àwa ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìdajì ènìyàn tí ó di ọ̀kọ̀ mú, láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yóò fi yọ.

  6. Ní ìgbà náà mo tún sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ dúró ní Jerusalẹmu ní òru, nítorí kí wọn le jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún wa ní òru, kí wọn sì le ṣe iṣẹ́ ní ọ̀sán.”

  7. Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn; wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn.

  8. Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn, inú bí i gidigidi; ó kọ Israẹli pátápátá.

  9. Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀, àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.

  10. Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn, dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.

  11. Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́, ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.

  12. Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn, àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:

  13. àfi àlùfáà wọn fún idà, àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.

  14. Saamu ti Asafu. Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ; wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́, wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.

  15. Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ, ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.

  16. Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi yí Jerusalẹmu ká, kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.

  17. Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká, àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.

  18. Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé? Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?

  19. Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀ rẹ, lórí àwọn ìjọba tí kò pe orúkọ rẹ;

  20. nítorí wọ́n ti run Jakọbu wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.

  21. wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, láti ìjọba kan sí èkejì.

  22. Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú; ó fi ọba bú nítorí tiwọn:

  23. “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi; má sì ṣe wòlíì mi níbi.”

  24. Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀; ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.

  25. Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́, kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.