Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The First Temple

365 ẹsẹ · 72 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn àlùfáà kò sì le wo ilé Olúwa náà nítorí pé ògo Olúwa kún un.

  2. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo Olúwa lórí ilé Olúwa náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú ni dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin Olúwa, wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa wí pé, “Nítorí tí ó dára; àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé.”

  3. Olúwa sì farahàn Solomoni ní òru ó sì wí pé: “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti yàn ibí yìí fún ara mi gẹ́gẹ́ bí ilé fún ẹbọ.

  4. Nígbà tí Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa, àti àwọn ìṣúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Solomoni dá.

  5. Ìdámẹ́ta yín níbi ààfin ọba àti ìdámẹ́ta níbi ẹnu odi ìdásílẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí ó wà ní àgbàlá ààfin ilé Olúwa.

  6. Nígbà tí Ataliah gbọ́ igbe àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sáré tí wọ́n ń kígbe ọba, ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn ní ilé Olúwa.

  7. Ní àkókò kan, Joaṣi pinnu láti tún ilé Olúwa ṣe.

  8. Ó pe àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ sí àwọn ìlú Juda, kí ẹ sì gba owó ìtọ́sí láti ọwọ́ gbogbo Israẹli láti fi tún ilé Ọlọ́run yín ṣe.” Ṣùgbọ́n àwọn ará Lefi kò ṣe é lẹ́ẹ̀kan náà.

  9. Nítorí náà ọba pa á láṣẹ fún Jehoiada olórí àlùfáà ó sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí o kò béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Lefi láti mú wá láti Juda àti Jerusalẹmu, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi lélẹ̀ àti nípasẹ̀ àpéjọ gbogbo Israẹli fún àgọ́ ẹ̀rí?”

  10. Nísinsin yìí, àwọn ọmọkùnrin obìnrin búburú ni Ataliah ti fọ́ ilé Ọlọ́run, ó sì ti lo àwọn nǹkan ìyàsọ́tọ̀ fún àwọn Baali.

  11. Nípasẹ̀ ọba, wọn ṣe àpótí wọ́n sì gbé e sí ìta, ní ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa.

  12. A ṣe ìkéde ní Juda àti Jerusalẹmu wí pé wọ́n gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa, owó orí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti béèrè lọ́wọ́ Israẹli ní aginjù.

  13. Gbogbo àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn ènìyàn sì yọ̀, wọ́n sì mú un wá, wọ́n ń jù ú sínú àpótí títí tí ó fi kún.

  14. Nígbàkígbà tí a bá gbé àpótí wọlé láti ọwọ́ àwọn ará Lefi sí ọwọ́ àwọn ìjòyè ọba, tí wọ́n bá sì rí wí pe owó ńlá wà níbẹ̀ àwọn akọ̀wé ọba àti ìjòyè olórí àlùfáà yóò wá láti kó owó rẹ̀ kúrò, wọn yóò sì dá a padà sí ààyè rẹ̀. Wọ́n ṣe èyí déédé, wọ́n sì kó iye owó ńlá.

  15. Ọba àti Jehoiada fi fún àwọn ọkùnrin náà tí ó sì ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Olúwa. Wọ́n fi owó gba ẹni tí ń fi òkúta mọ ilé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ilé Olúwa padà, àti àwọn òṣìṣẹ́ pẹ̀lú irin àti idẹ láti tún ilé Olúwa ṣe.

  16. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ náà, sì lọ síwájú àti síwájú ní ọwọ́ wọn, wọ́n sì tún mú ilé Ọlọ́run dúró sí ipò rẹ̀, wọ́n mú un le.

  17. Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fún ní ìpọ́njú dípò ìrànlọ́wọ́.

  18. Ahasi mú díẹ̀ nínú ìní ilé Olúwa àti láti ilé ọba àti láti ọ̀dọ̀ ọba ó sì fi wọ́n fún ọba Asiria: ṣùgbọ́n èyí kò ràn wọ́n lọ́wọ́.

  19. Ní oṣù àkọ́kọ́ ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, ó sì ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tún wọn ṣe.

  20. Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Lefi, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà-oòrùn.

  21. Ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin ọmọ Lefi! Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nísinsin yìí kí ẹ sì ya ilé Olúwa Ọlọ́run sí mímọ́, kí ẹ sì kó ohun àìmọ́ baba mi jáde kúrò ní ibi mímọ́.

  22. Àwọn baba wa jẹ́ aláìṣòótọ́; wọ́n sì ṣe ohun àìtọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Wọ́n sì yí ojú wọn padà kúrò ní ibùgbé Olúwa, wọ́n sì pa ẹ̀yìn wọn dà sí i.

  23. Wọ́n sì tún ti ìlẹ̀kùn ìloro náà pẹ̀lú, wọ́n sì pa fìtílà. Wọn kò sì sun tùràrí tàbí pèsè ẹbọ sísun si ibi mímọ́ si Ọlọ́run Israẹli.

  24. Nítorí náà, ìbínú Olúwa ti ru sókè wá sórí Juda àti Jerusalẹmu ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìdààmú àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i.

  25. Ìdí nìyí tí àwọn baba wa ṣe ṣubú nípa idà àti ìdí tí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti àwọn aya wa tiwọn kó wọ́n ní ìgbèkùn.