Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Spear

41 ẹsẹ · 26 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.

  2. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Na ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ sí Ai, nítorí tí èmi yóò fi ìlú náà lé ọ ní ọwọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua sì na ọ̀kọ̀ ọwọ́ rẹ̀ sí Ai.

  3. Wọ́n ti yan ọlọ́run tuntun, nígbà náà ni ogun wà ní ibodè a ha rí asà tàbí ọ̀kọ̀ kan láàrín ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ní Israẹli bí.

  4. A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí tí àwọn Filistini wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Heberu yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!”

  5. Bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ìjà ẹnìkankan nínú àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani kò sì ní idà, tàbí ọ̀kọ̀ ní ọwọ́; àfi Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani ni wọ́n ni wọ́n.

  6. Ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ rí bí apásá ìhunṣọ, orí ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì wọn ẹgbẹ̀ta (600) kilogiramu méje irin, ẹni tí ó ru asà ogun rẹ̀ lọ ṣáájú u rẹ̀.

  7. Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Saulu, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dafidi sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Saulu sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀.

  8. Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dafidi pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dafidi yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì.

  9. Saulu sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Saulu ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dafidi sì fi ara pamọ́ dáradára.

  10. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti Abiṣai sì tọ àwọn ènìyàn náà wá lóru: sì wò ó, Saulu dùbúlẹ̀ ó sì ń sùn láàrín kẹ̀kẹ́, a sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ ni ibi tìmùtìmù rẹ̀: Abneri àti àwọn ènìyàn náà sì dùbúlẹ̀ yí i ká.

  11. Abiṣai sì wí fún Dafidi pé, “Ọlọ́run ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí: ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, sá à jẹ́ kí èmi o fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, èmi kì yóò gun un lẹ́ẹ̀méjì.”

  12. Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Má ṣe pa á nítorí pé ta ni lè na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì òróró Olúwa kí ó sì wà láìjẹ̀bi?”

  13. Dafidi sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ Olúwa yóò pa á, tàbí ọjọ́ rẹ̀ yóò sì pé tí yóò kú, tàbí òun ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ìjà yóò sì ṣègbé níbẹ̀.

  14. Olúwa má jẹ́ kí èmi na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa. Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, mú ọ̀kọ̀ náà tí ń bẹ níbi tìmùtìmù rẹ̀, àti ìgò omi kí a sì máa lọ.”

  15. Ṣùgbọ́n ó sí kọ̀ láti padà, Abneri sì fi òdì ọ̀kọ̀ gún un lábẹ́ inú, ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀: òun sì ṣubú lulẹ̀ níbẹ̀, ó sì kú ní ibi kan náà; ó sí ṣe gbogbo ènìyàn tí ó dé ibi tí Asaheli gbé ṣubú si, tí ó sì kú, sì dúró jẹ́.

  16. Joabu sì wí pé, “Èmi kì yóò dúró bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ.” Ó sì mú ọ̀kọ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ́n gún Absalomu ní ọkàn, nígbà tí ó sì wà láààyè ní agbede-méjì igi óákù náà.

  17. Iṣbi-Benobu sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Rafa, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dafidi.

  18. Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní: Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ẹgbẹ̀rin (800) ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà.

  19. Abiṣai, arákùnrin Joabu, ọmọ Seruiah, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún (300) ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

  20. Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi asà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Juda àti Benjamini lábẹ́ rẹ̀.

  21. Jehoiada àlùfáà, sì fi ọ̀kọ̀ àti asà, àti àpáta wọ̀n-ọn-nì, tí ó jẹ́ ti ọba Dafidi tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run, fún àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún.

  22. Nígbà náà ó ṣiṣẹ́ gidigidi ní títún gbogbo ara ògiri tí ó ti bàjẹ́ ṣe, ó sì ń kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ gíga sókè rẹ̀. Ó kọ́ ògiri mìíràn sí ìta. Ó sì tún pẹ̀lú ibi ìtẹ́jú ilé ní ti ìlú ńlá Dafidi. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iye ohun ìjà àti àwọn àpáta.

  23. Nítorí náà mo dá ènìyàn díẹ̀ dúró níbi tí ó rẹlẹ̀ jù lẹ́yìn odi ní ibi gbangba, mo fi wọ́n síbẹ̀ nípa àwọn ìdílé wọn, pẹ̀lú àwọn idà wọn, àwọn ọ̀kọ̀ wọn àti àwọn ọrun wọn.

  24. Láti ọjọ́ náà lọ, ìdajì àwọn ènìyàn ń ṣe iṣẹ́ náà, nígbà tí àwọn ìdajì tókù múra pẹ̀lú ọ̀kọ̀, asà, ọrun àti ìhámọ́ra. Àwọn ìjòyè sì pín ara wọn sẹ́yìn gbogbo ènìyàn Juda.

  25. Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.