Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Spear

41 ẹsẹ · 26 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbí ọfà, ẹni tí ó ṣá a kò lè rán an.

  2. Ó ka ẹṣin sí bí àgékù ìdì koríko; ó rẹ́rìn-ín sí mímì ọ̀kọ̀.

  3. Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún; mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú, àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.

  4. Bá àwọn ẹranko búburú wí, tí ń gbé láàrín eèsún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà: tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká.

  5. Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn. Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

  6. Ẹ di ẹṣin ní gàárì, kí ẹ sì gùn ún. Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú àṣíborí yín! Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín, kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.

  7. Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun, wọ́n burú wọn kò sì ní àánú. Wọ́n n ké bí i rírú omi bí wọ́n ti ṣe ń gun ẹṣin wọn lọ. Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Babeli.

  8. Ẹ fi irin ìtulẹ̀ yín rọ idà, àti dòjé yín rọ ọ̀kọ̀. Jẹ́ kí aláìlera wí pé, “Ara mi le koko.”

  9. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì parí aáwọ̀ fún orílẹ̀-èdè alágbára jíjìn réré. Wọn yóò sì fi idà wọn rọ ohun èlò ìtulẹ̀ àti ọ̀kọ̀ wọn di dòjé orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

  10. Ológun orí ẹṣin ń fi ìgbónára ju idà wọn mọ̀nàmọ́ná ọ̀kọ̀ rẹ̀ ti ń dán yanran sí òkè! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ si ní àwọn ẹni tí a pa, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú; òkú kò sì ni òpin; àwọn ènìyàn sì ń kọsẹ̀ lára àwọn òkú.

  11. Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ ni ibùgbé wọn, pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ, àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.

  12. “Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dafidi àti sórí Jerusalẹmu, wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń ṣọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀.

  13. ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, lójúkan náà, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde.

  14. Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”

  15. Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ sí Kesarea, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹta òru.

  16. “Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀, gbogbo ojú ni yóò sì rí i, àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú”; àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni “yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.”